Ojo Aiku, Sannde to koja yii lokunrin omo bibi ilu Ijebu-Jesa, nipinle Osun naa ko rekoodu e tuntun to pe ni 'Ire-lo-ja-si jade', lati ibi gbogbo lawon eeyan ti waa ba olopolo pipe akorin esin naa ko awo re tuntun jade bii omo tuntun.
Saaju rekoodu to gbe jade yii, ni Efanjeliisi Asolo koko ti gbe rekoodu 'Unstoppable' jade lodun 2016. Opo awon olorin emi losere yii ti ba sere po, bee lo ti korin lopo ode ariya ati isoji.
Ileewe giga Osun State Polytechic, Iree lokunrin naa ti kawe jade ninu imo ibara-eni-soro. Efanjeliisi Seyi ti niyawo nile, bee ni Olorun fun un lawon omo alalubarika.
No comments:
Post a Comment