Lati aaro yii lawon eeyan ti n ba Aare Ona-kakanfo ile Yoruba, Iba Gani Abiodun Ige Adams daro iku baba e, Alagba Lamidi Adams to jade laye.
Ojutole gbo pe osibitu aladani kan to wa niluu Eko ni baba baa dake si leni ogorin odun.
Onisowo pataki ni Alagba Adams nigba aye e, ise awon onimoto lo koko se niluu Oturkpo, nipine Benue, ko too darapo mo ileese Desmony Nig. Ltd to je tawon oyinbo orile-ede Italy.
Oun ni adari awon to n mojuto eto irina oko nileese yii, nigba to kuro nibe lo da ileese tie naa sile.
Omo, omo-omo ati omo-omo-omo lo gbeyin baba to lo yii.
Ojutole naa ba Iba Gani Adams daro iku baba won, Olorun yoo fori gbogbo a i se deedee won ji won.
No comments:
Post a Comment