Ohun iyanu lo sele niluu Osogbo, lorun ana, okan ninu awon asofin ile igbimo asofin ipinle Osun, Onarebu Timothy Owoeye ni won ka mo ibi to ti n we ose dudu nihooho omoluabi ninu oja kan to wa lagbegbe Osunjela Satelite niluu Osogbo.
Okunrin yii to je omo egbe oselu APC ti won tun pe lolori awon asofin to poju nile igbimo asofin Osun lawon ode ka mo ibi to ti n we pelu ayajo buruku lenu.
Owoeye, to n soju awon eeyan Iwo-Ooru ilu Ilesa lo be awon ode to mu un yii pe ki won bo oun lasiri, tawon yen si n bi i leere pe ki lo de to fi se ohun to se yii.
Se lawon olode yii koko fi asofin yii sesin-in daadaa, ko too di pe won ni ko maa ba tie lo.
Sugbon ohun tawon kan so ni pe nitori ibo to n bo lona yii, lokunrin naa se gba odo awon alawo lo, ti won so fun un pe o gbodo we laarin oja to ba fee wole leekan si i.
No comments:
Post a Comment