AMBODE ATI WASIU NIGBA TI AARIN WON GUN |
Ninu iwadii ti Ojutole se lati mo pe nitori nnkan meta ninu Ambode se n bi Wasiu Ayinde gidigidi. Akoko ni pe latigba ti gomina ti gori aleefa lo ti keyin si Wasiu Ayinde, to je pe Olamide Badoo to n korin taka-sufee nijoba ipinle Eko n gbe ise orin fun.
Ikeji ni pe gbara ti Ambode dori aleefa ni ko ti gbe foonu Wasiu Ayinde mo, opo igba la gbo pe okunrin ti won n pe ni Arabambi awon onifuji naa ti pe Ambode lori foonu, sugbon ti ko gbe e.
Iketa ni pe Gomina ko ba Wasiu kedun nigba ti akobi e, Wasilat jade laye, a gbo pe Ambode ko pe e lori foonu lati ki i, bee ni ko ranse ibanikedun si i .
Gbogbo ohun ti a ka soke yii lo fa a ti inu se n bi Wasiu si Ambode, to si ti n wa ona ti yoo fi gbesan ohun ti Gomina se fun un yii. Boro wahala Ambode ati Tinubu se sele yii, ni K1 lo asiko naa lati gbesan iwa ti ko te e lorun ti Ambode hu si i yii.
No comments:
Post a Comment