IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 29 August 2018

IRO NI O, ARIYO PRODUCER KO KU OO, DIGBI LO WA

A fi da gbogbo eyin ololufe gbajumo producer awon olorin, Imaamu Musbaudeen Ariyo tawon eeyan mo si Ariyo Producer loju pe ko si kinni kan to se okunrin naa, Ariyo Producer wa laye, o wa laaye.

Ni nnkan bii aago meje ale yii lakoroyin wa ba Ariyo Producer soro, ohun ti okunrin naa so ree ' Haa, o ya emi naa lenu nigba ti emi naa ri i lori ero ayelujara pe mo ku , e ba mi so fawon fawon eeyan pe ko si kinni kan to se mi, mo wa laye, mo wa laaye. Eni to se bee, mo fa a le e Olorun lowo'

Se lokunrin kan gbe e sori intaneeti pe Ariyo Producer ku, ti eni naa tun gbe foto okunrin producer yii si i,pelu foto oku ti won di sile lati je kawon eeyan mo pe okunrin naa ti ku

.

Awa naa gbadura fun Ariyo Producer pe ko si iku kan ti yo o pa a, Olorun yoo je  ko dagba, ko si tun darugbo.

No comments:

Post a Comment

Adbox