IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 2 February 2018

Wasiu Ayinde ni yoo korin nibi ayeye 'Aje Festival' ti Iyalaje Toyin Kolade sonigbowo e

Taofik Afolabi


Oluaye awon onifuji, Alaaji Wasiu Ayinde Omogbolahan, tawon eeyan mo si Arabanbi, ni yoo korin nibi ayeye odun aje ti won pe ni 'Aje Festival' ti yoo waye nilu Ile-Ife, lojo kokandinlogun, osu keji, odun yii.

Ayeye nla yii ti Iyalaje ile Yoruba, Oloye Toyin Kolade, sonigbowo e ni yoo waye laafin Onirisa, niluu Ile-Ife, ni deede aago mewaa aaro. Orin aladun ati ilu to gbamuse loga awon onifuji yii yoo fi da awon eeyan lara ya lojo yii.

Aaro ana lakowe  ayeye naa, Oloye  Idowu Salami ati Oloye  Oyeyemi Oriowo (Sarun Oodua ) sabewo si Wasiu Ayinde nile e to wa ni Ijebu-Ode lati je ko mo pe oun ni yoo korin nibi ayeye yii.

Lasiko to n ba wa soro nipa ayeye yii, Oloye Toyin Kolade so pe ojo nla tawon omo Yoruba ko ni i gbagbe lojo naa. O waa ro gbogbo awon ojulowo omo Oodua lati peju-pese sibi ayeye yii .

No comments:

Post a Comment

Adbox