Latowo Taofik Afolabi
Loruko gbogbo awa osise ileese magasinni Iroyin Ojuole la fi ki eeyan wa pataki, ilu mo on ka akorin nni, Oloye Yinka Rythmz, ti gbogbo aye tun n pe ni Omo Somebody ku oriire ayeye ojoobi re to waye lonii.
A ki Atolase pe ojo oni soju re, adura wa ni pe titi aye loju re yoo maa rire, nitori pe ire bayii loju owo ri. Tokantokan la fi sadura fun Oluomo pe ibanuje aye ko ni i kan yin, e o ni i rogun wahala ati idaamu, peregede aye ko ni i lu fun yin jo, ole ara, ole emi ati ole dukia ko ni i ja yin lagbara aseda.
Atolase ti wa, e ti sodun eleyii naa, e o semi-in ninu ola, owo,ola ati alaafia ara. A yo fun yin, a yo ara wa. Igba odun, odun kan ni sa.
No comments:
Post a Comment