
Taofik Afolabi
Ti ki i ba se yiyo Olorun, ajalu nla mi-in ko ba tun sele lagbo awon osere tiata Yoruba wa, pelu bi okan ninu won, Adekunle Ayanfe, tawon eeyan mo si Aafa Monsuru ninu fiimu se nijamba moto.
Gege bi a se gbo, oko ere losere apanilerin-in naa n lo ti moto jiipu to wa ninu e nijamba, ti gbogbo iwaju oko naa si run, bee ni Ayanfe naa fi oju osi e se se, ile iwosan lokunrin naa wa to ti n gba toju lowo di bi a se n soro yii.
Okan ninu awon osere egbe e, Lawal Rukayat, lo je kawon eeyan mo ohun to sele si i , oun lo gbe aworan ibi ti Ayanfe ti wa losibitu ati moto to baje ohun sori ero ayelujara.
Okan ninu awon osere alawada tawon eeyan feran daadaa lokunrin yii, oun ati Okunnu ni won jo maa n saaba kopa ninu fiimu. Ileewe girama 'Ajibode Grammar School' lo ti kawe girama, to ko too tun kawe gboye ninu imo ere ori itage ni yunifasiti Ibadan.
No comments:
Post a Comment