IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 23 February 2018

Ko si egun kankan lori Aare Ona-kaka-nfo-Aare Gani Adams

Aare Ona-kakanfo tuntun, Aare Ganiyu Ige Adams ti so o di mimo pe ko si eegun kankan lori eni to ba je oye Aare Ona-kaka-fo gege bawon kan se n gbe e kiri pe eni to ba joye yii ki i pe e laye.

Aare soro yii lasiko ayeye Gb'aareniyi Day' to n lowo ninu ogba 'Blueroof' to wa ninu ogba ileese LTV, Ikeja.

Aare ni itan ati eri fi han pe aare ona-kakan-fo meje ni won pe laye daadaa, ti won darugbo kujekuje lori oye naa. Aare fi kun oro e pe aheso oro ni pe awon to ba  joye yii ki i pe laye, Aare ni bii ileese nla ti yoo maa ran awon to ku die kaato fun lowo, loun yoo se oye Aare Ona-kaka-fo, ti yoo mu ilosiwaju nla ba gbogbo omo Yoruba pata.

Aare te siwaju si i pe oun nilo iranlowo awon oba alaye, awon oniroyin atawon ti idagbasoke ile Yoruba ba je ogun lati ran oun lowo lori ise nla toun gbe dani yii.

Aare Adams tun so pe Olorun mo on lo Alaafin Ilu Oyo, Alayeluwa Oba Lamidi Adeyemi lati se opo atunto sile Yoruba ni.  

No comments:

Post a Comment

Adbox