IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 3 February 2018

IFEOLUWA BREAD NI: MO JIYA KI N TOO JEEYAN NIDII ISE BUREEDI, EMI O KI N GBO OLORIN MI-IN LEYIN PASUMA



Latowo Taofik Afolabi

Okan ninu awon ileese bureedi to gbajumo daadaa nipinle Eko, paapaa niluu Ikorodu ni 'Ifeoluwa Bread to wa lagbegbe Carnifonia, niluu Ikorodu, bii isana eleeta  ni bureedi naa gbajumo, to si tun gbeye mo gbogbo awon bureedi yooku lowo.

Laipe yii ni Iroyin Ojutole  sabewo sileese naa, ti a ba oga-agba ileese Ifeoluwa Bread, Ogbeni Nurudeen Abioye soro. Ojo naa lo salaye irin-ajo Ifeoluwa Bread, awon ipenija to ba pade, bi bureedi naa se gba ipo kin- in- ni fun wa
 atawon nnkan mi-in  nipa ti ko so fun oniroyin kankan ri laye.
Bi iforowero ohun se lo ree


Ojutole: E  daruko yin fun wa lekunrere

Ifeoluwa Bread: Oruko ti gbogbo aye mo mi si ni Ifeluwa Bread, sugbon oruko tawon obi mi so mi ni Nurudeen Abioye, omo bibi ilu Iwo, nipinle Osun ni mi, sugbon ilu Eko ni won bi mi si.

Ojutole: Okan gboogi ninu awon bureedi to gbajumo daadaa niluu Eko, tawon eeyan si feran daadaa ni Ifeoluwa Bread, bawo nirin ajo yin se bere nidii ise bureedi

Ifeoluwa Bread: Mo dupe fun Olorun lori ibi to gbe mi de lonii, nitori pe mo jiya nidii ise bureedi ki n too debi ti mo de yii. Ile ta si i tawa naa ti wa lenu e, ki i se ohun ti mo le royin tan. Ipata ati omo lile ni mi nigba ti mo wa ni kekere . Omo odun merindinlogun ni mo wa ti mo fi sa kuro nile, bi mo se pari iwe girama lawon obi fi mi senu ise mekaniiki, sugbon idojuko ti mo ba pade nibe lo je ki n sa lo sagbebe Oyingbo, ore mi kan toruko n je Saidi ni mo loo sa ba nibe. Bi mo se de Oyingbo ni mo ti fi ara mi senu ise mekaniiki ti mo ti sa kuro yii.

Sugbon nitori pe ki n ma ba jale lo je ki n loo sise bureedi, owo ti mo n ri nidii e ni mo fi n jeun,ti mo fi n ra aso sara. Lojo kan lokan ninu awon egbon wa ladugbo toruko won je Lekan so pe ki n wa maa bawon wa moto ti won fi n sopulai bureedi fawon onibaara won, bi mo se bere pelu won niyen. Mo je enikan to lakinkanju, nnkan si ma n tete ye mi. Odo booda Lekan yii ni mo wa ti wahala fi sele laarin awon ati mama to ni ileese bureedi ti mon fi moto sopulai bureedi fun yen. Wahala yen lo je ki booda Lekan sa lo, tawon to sunmo mama  yii so pe won o gbodo je kemi naa sa lo. Ohun ti mo so fun won nigba naa ni pe ko si ohun ti yoo mu mi sa nigba ti mi o jale won. Isele yii nibere oriire mi nidii ise bureedi.

Lojo kan ni mama to ni ileese bureedi yen fun mi lowo pe kemi naa fi maa n se bureedi temi, bi emi naa se di eni to n se bureedi jade niyen. Sugbon mo tun bawon idojuko kan pade, ohun to sele nigba naa ni pe awon bureedi ti mo n se jade ki i dara. Wahala yen lo je ki n so fun mama onileese yen pe mi o se bureedi mo, ohun to gbe mi kuro ni Oyingbo niyen.

Bi mo se de Ikorodu ni mo tun sise  nileese bureedi oga wa kan toruko won n je Ayo ni mo fe. Lojo kan lawon naa tun da gbogbo wa duro,won ni enikan ji batiri jenereto awon. Won pe wa pada lati  maa ba ise wa lo, sugbon mo so fun won mi o sise mo ni temi. Ko too di pe won da wa duro yii, mo ti ra awon agolo ti won maa n se bureedi yen pe emi naa fee maa se bureedi temi.

Ileese bureedi kan wa ni  Irese nigba kan, ohun ti won so fun mi pe awon ti won sise nibe ko se e daadaa leni to ni se ti i pa. Mo so fun ara mi lojo naa pe ibi ni mo ti sayeyori nidii bureedi ree. Bi mo se tun gbogbo e se niyen, temi ati ore mi kan toruko e n je Waheed bere ise nibe. Bi a se sise die lore mi so pe oun naa fee da duro, mo fun ni fulawa atawon eroja mi-in to nilo, mo se ku emi nikan niyen.

Ore mi yii gan-an lo fun mi loruko Ifeoluwa Bread ti mo n je yii, oruko naa lo di ohun ti gbogbo aye mo mi si bayii, opo eeyan ni ko mo oruko tawon obi so mi. Nigba ti mo tun bere Ifeoluwa Bread yii naa, mo tun pade awon ipenija nla. Fun apeere, masinni le baje, bureedi le ma jade daadaa, sugbon a dupe pe Olorun gba gbogbo ogo. Ohun to dun mi ju ni pe iya mi ti ku,nitori pe iya mi jiya pupo lori mi, ki Olorun ba mi fori ji won.

Pelu ogo Olorun, a ti ni ileese bureedi nla meji, mo ti kole, mo niyawo alalubarika kan, mo si bi awon omo oloriire.



Ojutole: Lara ipenija tawon onibureedi n koju lawon ajo NAFDAC, ogbon wo le n da soro won?

Ifeoluwa Bread: Mo dupe lowo awon egbe wa,awon ni won ba wa seto yen. Gbogbo ohun ti ajo NAFDAC so pe ka se la se pata.

Ojutole: Bureedi po niluu Eko,ki lo mu bureedi Ifeoluwa tayo awon yooku?

Ifeoluwa Bread: Mi o fise mi sere rara, gbogbo ohun to ba ye ki n lo mo n lo, mi o ki n maneeji ni temi. Nibi ti mo feran ise yii de, mo maa n lalaa bureedi loju oorun.

Ojutole: Se e le se ise mi-in yato si ise bureedi?

Ifeoluwa Bread:Laelae, ise bureedi yii ni mo ma se ku, ko si ise mi-in ti mo le se ju ise yii lo.   

Ojutole: Bawo le se pade iyawo yin?


Ifeoluwa Bread: Alalubarika obinrin, obinrin to ni laari ju awon obinrin yooku lo. Ibeere nla le beere yii o. Ibi ti mo ti kose lodo Ayo ni mo fe ni mo ti ri i.O  fi mi sako daadaa, emi ti mi o n ni nnkan kan lowo  nigba naa.Mo ran awon eeyan si i, mo be e  ko too gba fun mi, nigba ti oun naa ri i pe akinkanju okunrin ni mi lo gba fun mi. Nigba ti a n fera yen, oun gan-an lo maa n fun mi lowo, o maa n serun nigba naa.

Ojutole: Won le e feran Pasuma gan-an, se loooto ni?

Ifeoluwa Bread: Ha,nomba 1 le daruko yen, Oga Nla fuji, Sheu gbogbo won, omo alalubarika ti gbogbo aye n fe. Bi e se n wo mi yii, mi o ki n gbo orin mi-in, ti e ba ri rekoodu olorin mi-in nile mi, ki e pa aja fun mi je. Iyawo mi to feran Malaika gan-an, mo ti soo di ololufe Pasuma bayii, bee lawon omo mi naa. Ki Olorun ma pa Pasuma fun wa. 
    




      

No comments:

Post a Comment

Adbox