IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 21 February 2018

Gbajumo osere fuji, Obesere, ti bale si London,yoo forin aladun dara nibe

Bi e se n ka iroyin yin, ilu London ni gbajugbaja olorin fuji nni, to tun je oga-agba awon olorin patapata, Alaaji Abass Qudus Akande ti gbogbo aye mo si Obesere wa bayii nibi to ti n mura sile fun faaji nla to fee sele lojo Eti, Fraide, ojo ketalelogun osu yii.

Faaji nla yii yoo waye ni 'Unity 12, Thomas Road, Industrial Estate, E-14 7BA'. Lati aago mejo ale dojo keji kelele lariya yii yoo fi waye.

Obesere tawon eeyan tun mo si Paramount King of Fuji ti fawon ololufe e ni London ati ni gbogbo Yuroopu bale pe didun losan yoo so fun won lojo yii. O loun ti ko opolopo orin aladun,asa ti ko  legbe ati alujo ti ko wopo wa fun won.



 

No comments:

Post a Comment

Adbox