Ojoojumo ni wahala awon fulani darandaran ti won n pa awon agbe,ti won tun n se awon eeyan lese n po si i. Awon odaju naa ti gbe ise ibi won de ipinle Ogun bayii.
Gege bi a se gbo, aaro ojo Tosde ni won ko lu awon oluko kan lasiko ti won n lo sileewe, laduugbo kan ti won pe oruko re ni Atola junction, Onigbedu nijoba ibile Ewekoro.
Lojiji la gbo pe won yo si awon oluko ti won kolu won pelu awon ohun ija oloro, kawon eeyan yii too mo ohun to n sele ada ati obe ti n dahun lara won, Olorun lo so pe won ko ni i riku ojiji he lojo naa.
Awon eleyinju-aanu ti won ri won ni won sare gbe won lo sile iwosan nibi ti won ti n gbatoju lowo bayii. Bakan naa la gbo pe awon odaju fulani yii tun ko lu awo oluko labule kan ti oruko ren je Bada nitosi Opeji si Mawuko, yannayanna ni wo sa awon naa.
Ninu oro egbe awon oluko nipinle Ogun ni won ti benu ate lu ohun tawon fulani yii se,won ro ijoba lati gbe igbese lori awon apaayan yii,ki won to se ohun ti yoo lagbara ju beeyen lo.


No comments:
Post a Comment