IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 8 September 2025

Arẹgbẹṣola ro awon omo egbe ADC lOsun lati gba kaadi idibo

Pitimu ni inu gbọgan kan ti Ọgbẹni Rauf Aregbesola ti ma n ṣe ìpàdé ẹgbẹ Ọmọluabi ti o da silẹ káàkiri ile Yoruba loṣooṣu kuń fọfọ pẹ̀lú ọpọlọpọ awọn afenifere re ni ọjọ àìkú Sunday .
    T'ijo t'ilu ni àwọn ololufe bàbà náà fi pàdé rẹ, tí wón sì  fi orin oniranran gbé wo ilu gbọgan ohun.
    Ṣáájú ni Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla ti kọkọ dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ to wa nikalẹ pe won ku afọmọ níyànjú ṣe, tí ó sì gba ladura wipe àjọṣe gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa ko ni bajẹ 
     Leyin èyí ni Alàgbà Arẹgbẹṣọla wa gba gbogbo ọmọ ẹgbẹ ni ìmọ̀ràn pe o se pàtàkì fún wọn láti dára pọ mọ ètò gbigba káàdì ìdìbò ti o n lọ lọwọ nítorí ọmọ ẹgbẹ ti o ba ni káàdì ìdìbò lọwọ nikan ni o wúlò fún ẹgbẹ rẹ .
   Arẹgbẹṣọla salaye wipe ọmọ ẹgbẹ ti ko ba ni káàdì ìdìbò lọwọ kan dàbí abanikunjo ti ko ni ohun rere pàtàkì tí ó lè ṣe fún ẹgbẹ rẹ ti àsìkò ìdìbò ba de 
    Alàgbà Rauf ko sai fi ọkàn àwọn alatileyin rẹ balẹ wipe o da ohun lójú gbangba wipe ẹgbẹ òṣèlú ADC ni ẹgbẹ ti yoo gba gbogbo ọmọ orilẹ-ede Nàìjíríà kúrò labẹ isejoba amunisin ti ẹgbẹ APC ko gbogbo wọn da si.
       Lẹ́yìn èyí ló wà rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ pátá láti má fi gbogbo igba kéde fún gbogbo ènìyàn nípa bí ẹgbẹ oselu ADC ti ṣetan lati gba ìjọba kúrò lọwọ ẹgbẹ oṣelu ti o n dárí orilẹ-ede yii báyìí lai ṣe jagidijagan rárá ṣùgbọ́n nípa bíbá àwọn ènìyàn sọrọ  pẹ̀lú sùúrù àti ìwà Ọmọluabi

No comments:

Post a Comment

Adbox