Rauf Arẹgbẹṣọla ṣayẹyẹ ọjọọbi ọdun karundinlaadọrin iyawo ẹ, Ṣẹrifat lara ọtọ ni Eko
Ṣe ni ori ọpọ awọn eeyan to wa nibi ayẹyẹ ọjọọbi karundinlaadọrin ti Iyaafin Ṣẹrifat Abidemi Arẹgbẹṣọla, aya gomina nipinlẹ Ọṣun, bẹrẹ si ni wu nigba ti Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ọkọ oninawo ọjọ naa bẹrẹ ṣi nii sọrọ iwuri fun iyawo ẹ.
Ayẹyẹ ọhun to waye niluu Eko ni ẹsẹ ko ti gba ero nigba tawọn oloolufẹ ati alatilẹyin Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, akọwe apapọ fẹgbẹ oṣelu ADC, waa ba iyawo agba oṣelu naa ṣọjọọbi.
Ninu ọrọ iwuri ọhun ni Arẹgbẹṣọla ti sọ pe 'Aya mi tootọ, mo ki ọ ku oriire ayẹyẹ ọjọọbi to n ṣe.
" Mo dupẹ lọwọ Allah pe o fun mi ni oore ọfẹ lati ba ẹ ṣajọyọ ọjọọbi lonii pẹlu idunnu ati alaafia.
" Ni temi ki ka ọjọ ori kọ lọ lo ṣe pataki bi ko se idunnu ati ayọ ẹ to mu inu ẹ dun lo si jẹ ki inu temi naa dun.
" Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o jẹ ki ọjọ onii wa fun iranti rere, fun oore ọfẹ to fun wa taa wa ni iṣọkan ninu ibukun alilopin to fun wa.
O waa gbadura fun un pe ki Ọlọrun tunbọ lọra ẹmi ẹ pẹlu ayọ ati alaafia pipe.
Bẹẹ lọpọ awọn to wa nibi ayẹyẹ ọhun ni wọn ṣapejuwe Alaaja Ṣẹrifat Abidemi Arẹgbẹṣọla, gẹgẹ bi aya rere lọọdẹ ọkọ,to si maa n fi adura ran ọkọ ẹ lọwọ ni gbogbo igba.
Wọn lobinrin naa tun jẹ ẹlẹyinju aanu,ti o ko awọn eeyan mọra pẹlu adura pe ki Ọlọrun tubọ lọra ẹmi ẹ.

No comments:
Post a Comment