Olori ẹbi Papa Alagbẹji, niluu Isọlọ, nipinlẹ Eko, Oloye Taorid Farounbi ti gbogbo aye mọ si Alado ti rọ gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Olusọla Babajide Sanwo-Olu, igbakeji ẹ, Dokita Kadir Hamzat ati kọmisanna to n ri si ọrọ oye jijẹ nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Bọlaji Robert pe ko sẹni meji toun fọwọ si lati jẹ ọba ilu Isọlọ ju Ọmọọba Saheed Ishọla Arẹgbẹ lọ. Akinrogun ilu Isọlọ ni ko si ohun to da gomina duro lati gbe ọpa aṣẹ ọba ilu Isọlọ fun Arẹgbẹsọla lọ, nitoripe oun nikan ni gbogbo awọn fọwọ si, ko si ẹlomi-in tawọn n fẹ nipo ọba Isọlọ to ju Arẹgbẹsọla lọ, nitoripe ọmọ oye to kun oju osuwọn, to si fẹran awọn eeyan ilu ẹ ni.
Oloye Taorid fi kun ọrọ ẹ pe ẹnikan ṣoṣo toun tọwọ bọwe fun gẹgẹ bi ẹni ti yoo gori apere Ọsọlọ ni Ọmọọba Arẹgbẹsọla, ọkunrin naa si ni gbogbo ẹbi fọwọ si.
O waa rọ gomina ipinlẹ Eko, igbakeji ẹ ati kọmiṣanna fun ọrọ ọba jijẹ nipinlẹ Eko lati tẹle ifẹ ẹbi ati toun toun jẹ olori ẹbi, ki wọn ma jẹ kawọn eeyan gbẹyin ba ẹbọ jẹ, ki wọn ma si da wahala silẹ niluu Isọlọ.
Oloye Alado ni ‘ Emi Taorid, ọmọ Farounbi olori ẹbi Alagbẹji, mo tọwọ bowe pe Saheed Ishọla Arẹgbẹsọla ni gbogbo wa mu gẹgẹ bi ẹni ti yoo gori apere awọn baba nla wa, mi o tọwọ bowe fun ẹlomi-in yatọ si Saheed Arẹgbẹsọla.
No comments:
Post a Comment