Ojiṣẹ Ọlọrun nni, Primate Babatunde Elijah Ayọdele, oludasilẹ ijọ ẹmi Ajihinrere INRI, to wa niluu Eko, ti sọ pe ipakọ ko gbọ suti loun fi ọrọ awọn to ba n tako awọn aṣọtẹlẹ toun maa sọ, nitori oun nigbagbọ pe ọdọ Ọlọrun lawọn nnkan toun maa n sọ ti n wa.
O sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin fọrọjomitoro lori aṣọtẹlẹ ọdun to n bọ, eyi to waye ni ṣọọṣi ẹ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ana. O sọ pe oun kọja ẹni to n sọrọ sita tabi lori ẹrọ ayelujara, toun yoo tun sọ fawọn ọmọ ijọ oun pe ki wọn lọọ gbe ọrọ naa lẹyin.
Bẹẹ loun ki i di oniroyin lọwọ pe bawo ni nnkan to kọ nipa oun, nitori nnkan to ṣe pataki si oun ni pe gbogbo nnkan toun sọ ọdọ ọlọrun lo ti wa, ki i ṣe ọdọ eeyan. Ohun to ba si sọ, o sọ niyẹn, to ba si tun ni bẹẹ kọ, bẹẹ kọ naa ni.
Ojiṣẹ Ọlọrun naa tun sọ pe ti aṣọtẹlẹ ibi kan ba waye, Ọlọrun le yi i pada nipasẹ awẹ ati adura, ki nnkan naa ma ba ṣẹ ẹ. Ko sẹni to sọ pe dandan ki asọtẹlẹ aburu wa di mimusẹ Adura lo sọ pe o le yin nnkan pada.
Bakan naa lo fi aidunnu ẹ han lori iha ti ẹgbẹ awọn onigbagbọ iyẹn CAN, n kọ si ọrọ oṣelu to n lọ lọwọ lorileede yii, o sọ pe kaka ki wọn bẹbẹ fun itọsọna lati ọdọ Ọlọrun lori awọn oludije, ko yan adari rere fun wa, ti yoo mu wa delẹ ileri, ṣe lo ni wọn n lọ fikunlukun pẹlu awọn adije dupo ọhun, eyi to sọ pe o buru ju. O ni ko si nnkan to n ṣe daadaa mọ nitori Buhari ti kuna patapata.
Ayọdele tun sọ pe,’’ Naijiria ti loyun oṣelu lakooko yii,nnkan ta a ko ro ṣi le waye, mi o nii oludije ninu awọn to n dupo yii. Ṣugbọn Ọlọrun fi han mi pe ti Atiku ba wọle fun ipo aarẹ ọrọ aje wa yoo gberu si,to ba si jẹ pe APC, lo wọle, ti Tinubu jawe olubori,orileede yii yoo dara diẹ. Ti ẹgbẹ oṣelu Labour ba si wọle, ijọba awọn talika ni, nigba tawọn olowo yoo si maa pariwo. Ijọba PDP yoo wa fawọn olowo atawọn talika amọ tawọn ọlaju atawọn ara igberiko yoo gbadun ninu ijọba APC’’.
Bẹẹ lo tun sọ pe nnkan ti wọn fi han oun ni gbogbo ọna ni ẹgbẹ oṣelu APC , yoo lo lati ri I pe wọn jawe olubori ninu ibo to n bọ yii. Ṣugbọn oludije aarẹ PDP ati Labour, ko fi bẹẹ kọbiara to.
OjIṣẹ Ọlọrun tun sọ pe’’ Mo ri i pe agbara ilẹ Hausa pin si yẹlẹyẹlẹ, laarin awọn oludije mẹtẹẹta yii Obi, Tinubu ati Atiku. Awọn kan yoo fi ifẹ wọn han si Obi, nigba tawọn kan yoo sọ pe Atiku ni nigba tawọn Emir,si wa lẹyin Tinubu. Mi o ri awọn agba Hausa lẹyin Tinubu, bẹẹ ni mo tun ri i pe wọn dalẹ oludije APC yii, koda awọn to sunmọ ọn.’’
‘’Ẹ ẹ ma ṣi mi gbọ o, mi o ki i ṣe ọta Tinubu, bi wọn ba fi da temi, o tẹ mi lọrun ko wọle ju awọn yooku lọ, amọ nnkan ti Ọlọrun fi han mi niyẹn. O nilo aabo Ọlọrun. Ki i ṣe gbogbo awọn to n dije yii ni wọn yoo wa laye lọjọ ti wọn ba fẹ dibo, bẹẹ si ni ki i ṣe gbogbo awọn to jawe olubori ni wọn ma ṣe ibura fun, bakan naa ni mo ri i pe ọpọ awọn ti wọn ṣebura fun ni wọn ko pari saa wọn’’
Bakan lo sọ pe bi ijọba ko ba tete mura o ṣe e ṣe ki ẹgbẹ awọn olukọni ASUU, tun gun le iyanṣẹlodi, ninu ọdun ta a fẹ mu yii, nitori wọn ko ni le mu adehun awọn eeyan ọhun ṣe, eyi to si le mu kawọn ọmọleewe tun pẹ nile.

No comments:
Post a Comment