Johnson Akinpẹlu
Gbọngan aṣa ibilẹ, Cultural Centre, to wa niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun ko gbero lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, nibi ayẹyẹ igbominira awọn ọmọọṣẹ gbajumọ onitiata nni Yọmi Fabiyi, labẹ ileewe to da silẹ eyi to pe ni ROCKLAF Studio film Accedamy.
Ohun to jẹ ki eto ọhun tun fi dun yungba ni bi awọn agba oṣere onitiata ṣe peju sibẹ lati waa yẹ si lọjọ naa. Lara awọn oṣere ọhun ni Alaaji Kareem Adepọju tawọn eeyan mọ si Baba Wande, Adewale Ẹlẹsọ, aarẹ fẹgbẹ awọn oṣere tiata ANTP, Alagba Adedeji Ọlọfaana, Remmy shitta Bey, Alaaji Yinka Quadri, Rasak Ọyadiran, tọpọ mọ si Itu Baroka, Pari olodo, Kanran, Musiliu Dasọfunjo, Antar Laniyan, nigba ti Owolabi Ajaṣa, Gomina ẹgbẹ oṣere TAMPAN, naa ṣaaju awọn eeyan ẹ nipinlẹ Ogun wa sibẹ.
Bakan naa ni Ọnarebu Motunrayọ Adijat Adelẹyẹ-Ọladapọ, to jẹ kọmiṣanna fọrọ aṣa ati irinajo afẹ, nipinlẹ naa, ṣaaju ikọ tijọba wa sibẹ, nibi ti wọn ti ṣoju Gomina Dapọ Abiọdun. Ninu ọrọ ti Yọmi Fabiyi, oludasilẹ ileewe ọhun sọ lọjọ naa, lo ti dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aṣeyọri to jẹ kawọn fun ti ayẹyẹ igbominira to waye yii.
O sọ pe oun mu orukọ ileewe ọhun ROCKLAF jade gẹgẹ bo ṣe jẹ pe ọmọ Abẹokuta loun, to si je abẹ olumọ ni wọn ti fori oun sọlẹ iyẹn ni ROCK to ṣaaju, nigba ti LAF si jẹ apejẹ orukọ oun. O ba awọn ọmọ naa yọ pẹlu imọran pe ki wọn ma ṣe jẹ ki igberaga gbe wọn wọ lẹnu iṣẹ naa ati pe ki wọn ma ṣe yaju sawọn to ti jẹ agba nidii iṣẹ tiata.
Yọmi tun sọ pe tẹlẹ lawọn to gba yọnda naa jẹ ọmọọṣẹ amọ bayi ti wọn ti gbominira, wọn ti jọ di alabaṣiṣẹ pọ, ti wọn yoo si maa fi owo pe wọn si lokeṣan lati waa ṣiṣẹ. Bẹẹ lo tun bawọn obi wọn yọ pẹlu lori bi wọn ṣe fun wọn laaye lati kọ nipa iṣẹ tiata atawọn wọn to rọ mọ.
Remmy Shitta-Bey, to ti figba kan jẹ Gomina ẹgbẹ oṣere tiata ANTP, lo ṣe oro igbaniwọle fawọn akẹkọọ mọkandinlọgbọn ti wọn gba yọnda ọhun. Nigba ti Alaaji Yinka Quadri, fun wọn niwee ẹri.
Lọjọ naa tun ni wọn fun Gomina Dapọ Abiọdun ni awọọdu, Gomina to ṣe daadaa ju nipa ọrọ aṣa ati irinajo afẹ nigba ti Ọnarebu Motunrayọ Adija Adelẹyẹ- Ọladapọ naa gba awọọdu kọmiṣanna to ṣe daadaa ju lori asa ati irinajo afẹ.

No comments:
Post a Comment