IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 14 June 2022

N kò díje dupò lati lọo kówó jẹ rara, mo fee sin awon eeyan mi- Rukayat Shittu



Odomode oloselu, eni ọdun mẹrindinlọgbọn obinrin to n dije dupo aṣofin sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara ni Rukayat Shittu, omobinrin naa ti  ba BBC Yoruba soro.

Ninu oro e  lo ti salaye idi pataki to se fẹe dije dupo ni Owode Onire ati ohun to fee se fun awon eeyan ekun idibo e to ba wole gege bi asofin. 

' Mi o deeede ya sidii oselu,  o je ohun ti mo nifee si lati kekere,  Rukayat ni ife ti mo ni si awon eeyan mi lo je ki n gbegba oselu, mi o wa lati kowo je, sugbon lati mu aye irorun ba gbogbo awon eeyan agbegbe mi.

Mo fee fi asiko yii ro gbogbo awon eeyan mi lati fibo gbe mi wole, ki gbogbo wa le janfaani ijoba. Mo si tun dupe lowo gbogbo awon eeyan mi ninu egbe oselu APC fun bi won se yan mi gege bi oludije labe egbe oselu wa. Mo n fi asiko yii seleri fun won mi o ni ja won kule.


Ta ni Rukayat Shittu?

Ọdun 1996 ni wọn bi Omidan Rukayat Shittu.

O kawe gboye nile ẹkọ National Open University ni Naijiria.

O jẹ ọmọ bibi ilu Manyan ni Owode Onire ni ijoba ibile Asa ni ipinle Kwara ni aarin gbungbun Naijiria.

Rukayat salaye awọn ohun to gbe e dide ati bi ọpọ sẹ n satileyin fun un nipinle Kwara fun BBC Yoruba.



No comments:

Post a Comment

Adbox