Bi nnkan ṣe n lọ yii inu ọran nla ni gbajumọ olorin ẹmi nni, Ẹfanjẹliisi Tọpẹ Alabi wa bayii, ko si ohun to fa eyi ju orin olorin ti obinrin naa ta fun awọn ileesẹ ẹlẹrọ ibanisọrọ ‘MTN, Airtel ati Globalcom’ lọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọdun 2006 ni Tọpẹ Alabi tọwọ bowe adehun pẹlu ileeṣẹ NPC records and audio works to jẹ ti Alaaji Tajudeen Bioku to n gbe lorileede Amẹrika. Adehun ti obinrin naa ṣe pẹlu ileeṣẹ naa lati ṣe rẹkọọdu Angẹli mi lede Yoruba ati ede gẹẹsi fun wọn, ṣugbọn ti ede Yoruba nikan lobinrin naa ṣe to si gba owo iṣẹ ẹ lọwọ Alaaji Bioku.
Ohun mi-in to wa ninu adehun ti Tọpẹ ṣe lọdun naa lọhun-un ni pe oun ko lasẹ tabi ni ẹtọ kankan lori rẹkọọdu ọhun mọ ati pe gbogbo ẹtọ ati adehun rẹkọọdu naa jẹ ti ti ileeṣẹ Bioku ati Alaaji Bioku to ni ileesẹ ọhun. Bakan naa la gbọ pe owo gobọi ni Tọpẹ gba lori rẹkọọdu yii, eyi to tumọ si pe o ti ta ẹtọ ẹ eyi ti awọn oloyinbo n pe ni ‘right’ ẹ lori rẹkọọdu Angẹẹli mi yii.
Ṣugbọn si iyalẹnu ileeṣẹ to gbe rẹkọọdu yii jade ṣe ni gbajumọ akọrin ẹmi naa gbẹyin lọọ ta orin mẹta ninu rẹkọọdu naa, iyẹn Angẹẹli mi, Jesu Olurapada ati E gbe e ga fun awọn ileesẹ ẹlẹrọ ibaraẹnisọrọ MTN, Airtel ati Globalcom. Bakan naa la gbọ pe lati ọdun 2011 lawọn ileeṣẹ ẹlẹrọ ibaraẹnisọrọ yii ti n lo awọn orin yii gẹgẹ bii ‘ringi toonu’ ti wọn si ti gba owo rọburọbu lọwọ awọn onibaara wọn ti wọn n lo awọn orin yii gẹgẹ bii orin ti wọn n lo nigbakigba ti wọn ba ti pe wọn sori foonu wọn.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni nnkan bii ọdun meji sẹyin ni asiiri ohun ti Tọpẹ ṣe yii tu si ileesẹ NPC Records lọwọ, nitori ẹ ni lọọya wọn nigba naa, Oloye Bọlaji Mustapha ṣe kọ lẹta si awọn ileeṣẹ ẹlẹrọ ibaraẹnisọrọ mẹtẹẹta naa lọjọ kẹẹẹdogun osu kẹsan-an ọdun 2020, ṣugbọn ṣe ni wọn kọ eti ọgbọn si lẹta, bẹẹ nigba to tun di ọjọ kẹẹẹdogun osu keji ọdun 2021, lọọya ileeṣẹ NPC records tun kọ lẹta mi-in sawọn ileeṣẹ ẹlẹrọ ibaraẹnisọrọ naa, ṣugbọn bakan naa ni wọn tun ṣe.
Wọn ko duro sibẹ, nigba to tun di ogunjọ osu kẹwaa, ọdun 2021, agbjọro mi-in ti ileeṣẹ NPc Records gbe iṣẹ yii fun, iyẹn S.O Oyeniyi tun kọ lẹta mi-in sawọn ileeṣẹ to n lo orin yii, ṣugbọn bakan naa tun lọmọ sori, wọn ko da esin lẹta yii pada, bẹẹ ni wọn ko ṣe bii ẹni pe awọn gbọ nnkan kan nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn yii.
Nitori ẹ ni ileeṣẹ naa fi gba ile-ẹjọ giga iyẹn ‘Federal High court’ to wa ni Ikoyi lọ, nibi ti adajọ ti n gbọ ẹjọ ọhun lọ bayii. Owo tiye rẹ jẹ biliọnu kan aabọ Naira nileeṣẹ NPC Records beere fun niwaju adajọ lọwọ awọn ileeṣẹ ẹlẹrọ ibaraẹnisọrọ naa.
Ni bayii, adajọ ti sun ọjọ igbẹjọ mi-in si inu osu kẹfa, ti igbẹjọ yoo tun tẹ siwaju si i.

No comments:
Post a Comment