IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 17 April 2022

Adeyẹmi oludije gomina fẹgbẹ AA ki awọn eeyan ipinlẹ Ogun fọdun Ajinde


Dokita Samuel Adeyẹmi, oludije gomina fẹgbẹ oṣelu AA, nipinlẹ Ogun, ti ki awọn eeyan ipinlẹ naa ku ayẹyẹ ọdun Ajinde, to n lọ lọwọ.

Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita lo ti kesi awọn eeyan naa lati lo anfaani ọdun Ajinde yii ranti gbogbo iya ti Jesu Kristi jẹ lori igi agbelebu, to si farada gbogbo inira ati itiju.

O ṣalaye siwaju pe igbala ni Jesu fẹ gbogbo wa fun, nitori ki a le ni igbala ati irapada nla. O waa gbadura pe iku ẹ ko nii lọ lasan lori gbogbo wa.

Bakan naa ni oludije fẹgbẹ oṣelu AA, tun fikun ọrọ ẹ pe oun ṣetan lati mu ayipada rere ba awọn eeyan ilu, bi wọn ba le dibo yan oun wọlẹ gẹgẹ bi gomina fọdun 2023.

O ni gbogbo wa lapapọ la ni lati jọ le ijọba APC kuro lọdun 2023, lati le fopin si idaamu ti wọn ko ba awọn eeyan lojoojumọ. O ni o da oun loju pe orin ọpẹ ni yoo gba ẹnu gbogbo wọn laipẹ.

No comments:

Post a Comment

Adbox