Ọrọ kan to n lọ nigboro laarin awọn ololufẹ orin fuji lorileede yii ati loke okun ni pe ija abẹnu kan n ṣẹlẹ laarin awọn gbajumọ oṣere fuji meji nni, Alaaji Ṣaheed Oṣupa Akorede ati Seriki Akanji Adewale Barryshowkey. Ohun ti awọn to n gbe ọrọ yii kiri sọ ni pe agba-ọjẹ olorin fujji nni, Alaaji Shina Akanni Aroworeyin lo da ija ọhun silẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni inu n bi Osupa gidgidi si Barryshowkey pe ko ta si oun nigba ti o n wa si Amẹrika lati waa kọrin ati pe dipo ko ran oun ti oun jẹ ọmọ ilu ẹ lọwọ, Shina Akanni to jẹ ọmọ bibi ilẹ Ẹgba lo ṣe iranlọwọ fun lasiko ti agba ojẹ olorin fuji ti wọn n pe ni Skọpido naa waa kọrin lorileede Amẹrika, ọrọ yii wọn n lo ka Oṣupa lara to fi n binu si Barryshowkey, o ni ọkunrin naa dalẹ alajọbi.
Ṣugbọn ninu ọrọ Barryshowkey lo ti sọ pe ko si ootọ ọrọ kankan ninu ọrọ ti wọn sọ pe o da Osupa nu, o ni ọkunrin naa ko kan si oun nigba to de Amẹrika, oun kan gbọ pe o ti balẹ si orileede naa ni, oun ki i si da si ohun ti wọn ko ba pe oun si.
O ni loootọ ni pe gbara ti Shina Akanni de Amẹrika lo fi to oun leti, toun si lọọ ba nibi to ti kọrin. Ọkunrin ọmọ bibi ilu Ibadan yii sọ pe bi oun ṣe gbọ nipa awọn ti Osupa de si ọdọ wọn loun ti sọ pe awọn ti ko rẹsẹ walẹ daadaa lagbo ariya ni ọkunrin naa de si lọdọ.
Ninu ọrọ tiẹ, Shina Akanni ni, irọ to jina sootọọ ni pe Barryshowkey ba oun gba ere lasiko ti oun lọọ kọrin ni Amẹrika. O ni loootọ loun jẹ ki ọkunrin naa mọ pe oun ti gunlẹ si Amẹrika, to si waa ba oun nibi ti oun ti ṣere, ṣugbọn ko ba oun gba ode ere titi ti oun fi pada wa si Naijiria.

No comments:
Post a Comment