Ọkan gboogi ninu awọn ọba alaye ati ojulowo ọmọ Oodua ni Ọba Rasak Ademọla Adisa Onimọba tiluu Mọba Akẹran Mọba Ẹkun, nijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko. Laipẹ yii ọba nla yii gba oniroyin wa, Taofik Afọlabi, lalejo laafin wọn. Diẹ ninu ohun ti wọn jọ sọ ree
Itan wo lo tẹ ilu yii do, i bo ni ilu Mọba ti sẹ wa?
Ilu Mọba ti wa lati igba iwasẹ, lati aye baba nla wa Oduduwa, ilu to ni itan oriṣiriṣii, ti ọpọ ọba ti jẹ nibẹni, ti wọn si tẹ oriṣirisii ilu do ni ilu Mọba. Baba wa to n jẹ Olokun to n jẹ Oore ti ilu Mọba yii, nigba to n jade lọ, o ṣe ipinnu pe gbogbo ibi ti awọn ọmọ oun ba n de si Mọba ni ilu naa yoo maa jẹ, nigba to de ibi yii Moba naa lo sọ ọdọ wa yii naa.
Nigba ti oju n yọ baba nla wa Oduduwa lẹnu, nigba to de Ile-Ifẹ ti wọn difa pe omi okun ni wọn yoo fi wo oju baba nla wa san, ọmọ to kere ju laarin wọn iyẹn, Ajibokun, ti wọn n pe ni Ọwa Obokun lonii, ilu yii lo ti waa bu omi ti wọn fi tọju oju baba nla wa lati ile-Ifẹ.
Itan ti ko fẹsẹ mulẹ rara ni pe ọmọ kan ni Oduduwa bi, Okun ati Ọṣa ti ẹ n wo yii, iyawo Odududuwa ni wọn nigba iwaṣẹ, mi o fẹẹ sọrọ lọ sibẹ yẹn lonii. Onipopo, awọn yii lo tẹ ilu Ajasẹ do,bi wọn ṣe n bọ Onipopo ni Ajasẹ lawa naa n bọ ọ nibi nitori pe iran Akẹran ni wọn, lara ọmọ mẹta ti Asetu Ogiriọba bi fun Oduduwa ni wọn, orukọ awọn ọmọ naa ni Ẹlẹṣa, Akẹran to ṣẹ awa do, inu ile Oduduwa ni Akẹran sun. Gbogbo ọmọ ti Akẹran bi ni wọn jade sita lọọ jọba, bi ẹ ba de Igbajọ, ọba igbajọ, ọmọ Akẹran ni, awọn Omuaran ni Kwara, ọmọ Akẹran ni wọn, Olomu Akẹran ni wọn sọ di Olomu Apẹran, lara awọn ọmọ Akẹran ni Oore tilẹ Mọba nipinlẹ Ekiti lonii, Ẹlẹgan meje lara awọn ọmọ Akẹran ni. O ti le ni ẹgbẹta ọdun t wọn ti tẹ ilu yii do.
Awọn ọba wo lo ti jẹ nilu Mọba Akẹran ti a wa yii?
Bi ọmọde ko ba ba itan, yoo ba arọba, arọba si ni baba itan, ṣe ẹ mọ pe laye atijọ ki i ṣe ọwọ ijọba ni ọba ti n wa. O bẹrẹ lati ọba Onipopo to pada lọọ tẹdo si ilu Ajaṣẹ, Oore ti wọn n pe ni Oloore Oduduwa, Ẹlẹgan, Akẹran ko too wa a di aye ọlaju to jẹ pe ijọba lo n fi ọba jẹ. Ninu iran temi, mo si ranti awọn kan ti mo ti ara wọn jade, nigba ti ọlaju de orukọ ẹsin ni wọn n jẹ, lara wọn ni Ọmọawoye, Ogunlaaafin Ọmọfala, ara iran yii lawa ti jade. Awọn ti wọn yi orukọ wọn pada si orukọ musulumi nigba ti ẹsin musulumi de ni Ali, Buraimọ, Ashiru, Yisa, bẹẹ la ti ni ọpọ awọn adele obinrin ko too di pe o kan mi, ti mo gba ọpa aṣẹ baba nla mi.
Awọn ileewe wo ni kabiyeesi lọ?
Mo lọ si ileewe Ajerọmi Public Schoool, nilu Ajerọmi, nijọba ibilẹ Ajerọmi Ifẹlodun bayii, Lẹyin ẹ ni mo lọ si ‘Modern Career Techinical College’, mo tun lọ sileewe ‘Tecninical College ni Yabaa, ti mo ti kọ nipa ẹlẹtirika, bẹẹ ni mo tun ṣe eyi ti wọn pe ni Trade Test, ti mo fi ṣiṣẹ lawọn ileeṣẹ nla nla.
N jẹ ẹ ni lọkan pe ẹ o de ori itẹ awọn baba nla yin nigba ti ẹ wa ni kekere?
Mi o ni i lọkan, bẹẹ ni mi o gbọ ọ ri, ṣugbọn akiyesi ti mo ṣe ni pe nigba ti mo wa ni kekere mo fẹran ki n maa fi ilẹkẹ sọwo. Mo ranti daadaa pe lọdun naa lọhun-un, ṣe ni baba mi pariwo le mi lori pe ‘Rasak, ṣe o fẹẹ ṣe babalawo ni, iwọ ọmọ musulumi kin ni lẹkẹ n ṣe lọwọ ẹ, lọọ wa kupa tabi goolu ki o ma fi sọwọ’. Nigba ti mo wa si ilu yii, ni baba to bi baba mi sọ pe ki n ma da baba mi lohun pe ṣe ko mọ pe ọmọọba ni mi, wọn ni oun lo gba ẹsin ni tiẹ.
Mo tun ranti nigba ti mo wa ni kekere ni ti mo wa si ojubọ popo, mo ma n sọ pe emi ni mo jọba ilu yii, bẹẹ ere ni mo n ṣe nigba naa. Ki n too dori ipo yii ni mo ti joye lawọn ilu kaakiri, mo oye akọgun ni Alaba Suuru, bẹẹ ni Oniba tilu Iba to waja naa fi mi jẹ Aro tilẹ Iba, lẹyin ẹ ni wọn pe mi pe ki n waa joye awọn baba nla mi, wọn ni emi ti mo n ṣe gudugudud meje ati yaaya mẹfa nilu onilu ki n wa a tun ilu baba mi ṣe. Mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe lati igba ti mo ti de ilu yii lọkẹ aimoye ilọsiwaju ati idagbasoke ti n ba a, nitori pe inu igbo kijikiji ni mo ba ilu, awọn onileeṣe nla ti n wa da iṣẹ silẹ nilu mi.
A n ṣoselu, a n ba ijọba ṣe ki ilọsiwaju le ba ilu, mo dupẹ fun Ọlorun pe awọn to tẹ ilu Ifẹ mọ ipo ti Mọba wa, ko si Ọọni to jẹ ti ko mọ ilu yii, mo n ṣoju ilu yii lọdọ Ooni Ile-ifẹ ati ni ajọ ‘Common wealth’.
Ohun to ku bayii ni pe ki n gba ade isẹmbaye awọn baba nla mi, nitori pe ijọba ti kede sinu iwe iroyin pe awọn ti gbe ade fun ilu yii, ko too di pe awọn kan tun gba ile-ẹjọ lọ, ẹ ma jẹ ki n sọrọ pupọ lori ẹ.
Awọn ọdun iṣẹmbaye wo lẹ ma n ṣe nilu yii?
A n ṣe ọdun Mọba Onipopo, inu oṣu kẹta lo ma n waye, a n bọ Ọta, a n bọ odo Oorẹ, lara awọn ooṣa ti a ba lọwọ awọn baba nla wa niyẹn. Iru ẹja kan wa niluu yii to ti lo to ẹẹdẹgbẹta ọdun laye, iru ẹja to jẹ pe ọmọ kekere ko le da gbe.
Ajọṣepọ lo wa laarin ẹyin ati Ọọni Ile-Ifẹ?
Ajọṣepọ ọmọ si baba ni, ipo ọmọ si baba ni Mọba jẹ si Ile-Ifẹ.
A o ri i pe lẹnu ọjọ mẹta yii, awọn nnkan ti ko yẹ ko ṣẹlẹ si awọn ọba alaye lo n ṣẹlẹ si wọn, bii ki wọn ji ọba gbe. Oju wo lẹ fi wo eyii?
Ọtọ ni ẹsin, ọtọ ni isẹṣe, ṣugbọn a ti fọwọ yẹpẹrẹ mu isẹṣe, oyinbo fi ọgbọn gba ohun to dara lọwọ wa, nigba ti mo tẹle Ọọni lọ si Amẹrika, a ri awọn nnkan baba nla wa nibẹ, a ri awọn ade isẹmbaye to jẹ ti wa nibẹ ti wọn ko sinu aja-ilẹ, ti awọn oyinbo yii tọju wọn, mo ri oku eeyan ti ko jẹra. Bawo ni wọn ko ni i ji ọba gbe, ṣe aṣẹ si wa lẹnu ọba, agbara wa nilẹ Yoruba, a ri ẹni to wa sinu igbo oro wa yii to fọ loju pẹlu ohun to ri nibẹ, ko si ọba to ni ajẹsara mọ, ko sọba to ni agbero mọ. Ohun to fa a ti wọn ṣe n ji ọba gbe ti, wọn yinbọn fun ọba alade ree.
Kin ni ọna abayọ:
ka pada si nnkan tiwa, ka mu aṣa wa ni koko, ẹ ma jẹ ki wọn fi burẹẹdi ko wa lọbẹ jẹ, gbogbo nnkan ti a n jẹ pata oogun ni, ẹ ma jẹ ka tan ara wa, ka pada sidii iwasẹ.
Kabiyeesi, ẹ ṣe un. Awọn iṣẹ wo lo jẹ iṣẹ iwasẹ ilu yii?
Awa lọmọ onireke agbijo, ọmọ afedejayan ẹja, awa la a ni ounjẹ, awa naa lọmọ alagbọn, awa la a ni ẹni, ka pa ẹja, ka pa, akan, awa la ni agbọn.
Nigba ti a fẹẹ wọ inu aafin, a ri posita oloṣelu kan labawọle aafin, ṣe kabiyeesi ṣoṣelu ni?
Bẹẹ ni, ẹgbẹ APC ni mo n ṣe.
Awọn nnkan wo lo n jẹ ilu yii niya?
Mo n fẹ afara ti yoo jẹ ki ilu yii rọrun lati wa ati lati wọ, ti yoo mu ilọsiwaju ba ilu yii
No comments:
Post a Comment