IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 6 January 2021

Omo odun mejila ni mo wa ti mo ti n korin - Kemi Wonder




Okan gboogi ninu awon omo orile-ede yii ti won n gbe oruko Naijiria ga loke-okun ni Efanjeliisi Kemi Adeyale, ti gbogbo aye mo si Kemi Wonder.

Orile-ede Amerika lomobirin naa n wa to ti n fi ebun orin ti Olorun fun un jeere okan.

Laipe yii ni Kemi Wonder se iforowero raipe pelu Ojutole. Ninu iforowero ohun lo ti salaye fun wa pe omo odun mejila pere loun wa ti oun ti korin ninu egbe akorin ijo Anglican  tawon obi oun n lo.

Bakan naa lo salaye fun wa pe oun sese pari ise lori rekoodu oun akoko ti oun pe ni 'Victory'. Laipe yii lo so pe rekoodu naa yoo jade fun igbadun gbogbo awon eeyan. Awon orin imisi, orin ijeere okan lo so pe o kun inu rekoodu naa bamubamu.


Yato si ise orin, Kemi Wonder tun ni ileese ti won ti n ta ounje, yala ounje awon oyinbo tabi ti ile adulawo. Bee lo so pe awon tun ma a n ba awon eeyan se ounje fun ayeye won.

Gbajumo olorin emi, Sola Alyson ni Kemi Wonder pe ni awokose re nidii ise orin. O ni isowokorin obinrin naa wu oun pupo.

Ileewe alakobere ati girama   CAC Primary School ati Baptist Secondary School to wa ni Ile-Oluji, nipinle Ondo ni Kemi Wonder lo.

Obinrin yii wa a ro gbogbo awon ololufe e pe ki won tewo gba rekoodu oun naa to ba ti jade.

No comments:

Post a Comment

Adbox