Gbajugbaja
wolii agbaaye nni, Primate Babatunde Ayọdele
Elijah tijo ‘INRI Evangelical
Church’ to wa ni Oke-Afa nipinle Eko ti ju awon asotele odun 2020 sita. Lara awon asotele ti ojise Olorun yii so fun
wa lo ti so pe idaamu yoo wa fun awon
omo Naijiria ti won wa loke-okun, o ni ki won gbadura ki won ma ri ku he.
Nipa oro aje orile-ede yii, Ayodele so pe oro aje orile-ede yii yoo denu kole, o ni bo tile je pe ijoba yoo gbiyanju lati je ki oro aje se daadaa, sugbon igbiyanju ijoba ko ni i so eso rere. Ayodele ni ijoba ipinle Eko, Anambra, Enugu ati Imo yoo se atunse si owo ile. O ni ka gbadura ki ijamba bombu ma sele, ka ma ri iku ojogbon nla, adajo, gomina alagbada, minisita ati onisowo pataki nla kan. Wolii nla yii so pe owo epo gaasi yoo lo soke, bee ni sitoofu onina kan yoo jade.
O ni ‘ E je ka gbadura ki wahala ma sele
laarin awon eya Igbo, Hausa ati Yoruba.
Ka gbadura ki ikun omi ati omiyale agbara ya soobu ma sele lawon ipinle bii: Enugu, Kogi, Eko, Ondo ati
Ekiti atawon apa ibikan nile Hausa.
Wolii yii ni ijoba aare Muhammad Buhari yoo
tu asiri awon gomina atijo kan, ileese monamona ipinle Eko, River, Kwara, Kano yoo ni ipenija. Enubode ti ijoba
ti yoo je ki ise agbe lo soke daadaa,
ijoba yoo gbe awon igbese kan lori oro ohun ogbin eyi ti yoo so eso
rere.
E je ka gbadura ki
afara kan ma ja, ka gbadura ki akolu ma waye lati awon orile-ede ti won sun mo
wa. Tinubu yoo keyin Osibajo si ooru ale, wahala yoo sele laaarin Osibajo ati
Buhari, awon alagbara kan nile ijoba yoo fee yo Osibajo nipo, bee lawon
alagbara kan yoo dide ogun pelu Tinubu. Igbakeji aare gbodo gbadura gidigidi
nitori pe won yoo gbogun ti i E je
ka gbadura ka ma ri rogbodiyan ati ikolu lawon ipinle yii: Kano, Benue, Kaduna,
Ondo, Jigawa’. Ojise Olorun yii ni ka
gbadura ka ma ri ijamba oko ofunrunfu ati oju-popo, bee lo so pe ayipada yoo de
ba isakoso awon ileese oko ofunrunfu nipinle Eko, Kano ati Abuja.

No comments:
Post a Comment