Ohun ti a gbo bayii ni pe osere nla yii ti pari ise lori fiimu ijo alaso ara akoko iru e lorile-ede yii to pe ni 'Ilu Awon Agba', awon osere ti won lami-laaka ni won kopa ninu e.
Ojo keeedogun osu kejila ti a wa yii nifilole fiimu ohun yoo waye ni gbongan nla 'Sekious Hall' to wa ni Ebute, ni Ikorodu, niluu Eko.
Bakan naa la gbo pe idije ere ori itage laarin awon omo ijo alaso-funfun, iyen Sele ati Kerubu yoo waye lojo kewaa ati ojo kokanla osu yii. Ileewe ti won ti n ko nipa ere ori itage to je ti osere naa, iyen G10 pelu ifowosowopo ijo Sele, lagbaaye, iyen CCC International Headquarter to wa ni Ketu lo sagbateru idije yii.
Awon olorin nla, awon osere ti won loruko daadaa atawon eeyan pataki ni won n reti nibi ifilole fiimu yii. Fun alaye lekunrere, e pe Lagata sori nomba yii:08037279844
No comments:
Post a Comment