Gbogbo eto lo ti pari lori ayeye onibeta
ti okan ninu awon gbajumo osere tiata ile wa, Fadekemi Faith Adebayo
tawon eeyan mo si
Fadekemi Alara fee se. Ojo
kokandinlogbon, osu kejila yii layeye naa yoo waye ni gbogan nla ‘Koga Hall’ to
wa lojule keji, opopona Bolaji Close, Kudirat Abiola Way, Oregun, Ikeja.
Ayeye nla ohun ni ifilole fiimu e to
pe ni ‘Emi kan’,Fifun awon eeyan ni ami-eye ati ayeye ojoobi e. Awon olorin ti
won yoo dalu bole lojo naa ni: Oga Nla awon onifuji, Alaaji Wasiu Alabi Pasuma,
Efanjeliisi Paul Omo Abule, Small Doctor,
Eri Igboho, Ozo Fresh atawon mi-in.
Eni ti yoo tuko eto naa ni Baba
Labule ati Taofik Koyokoyo, nigba ti oba alaye ojo naa yoo je, Alayeluwa Oba
Babatunde Eniitan Ogunwusi Ooni Ileefe. Ankara ati jakard lawon eeyan yoo fi wole sibi ayeye yii, fun Ankara
ati jankard ti yin, e pe Fadekemi sori nomba yii:07068774560.
Ninu
oro Fadekemi lo ti ro awon ololufe e lati waa fi ojo naa ye oun si, o ni gbogbo
won pata ni won yoo gbadun ara won daadaa.
No comments:
Post a Comment