IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 30 December 2019

Gọngọ sọ lọjọ ayẹyẹ ọdun ACO Day ti Ọnarebu Shuaib Ajidagba ṣagbatẹru ẹ -Gbogbo awọn eeyan Ifẹlodun sọ pe aṣaaju gidi lọkunrin naa










Ọjọ nla ti gbogbo awọn eeyan ijọba ibilẹ idagbasoke Ajerọmi-Ifẹlodun ko ni i gbagbe bọrọ lọjọ Aiku,

Sannde, ana, idi ni pe ọjọ yii layẹyẹ ọdun nla ti wọn pe ni ACO Day ti
























alaga ijọba ibilẹ naa, Ọnarebu Fatai Shuaib Ajidagba ti gbogbo aye mọ si Ajidagba ṣagbatẹru ẹ waye, bamubamu lawọn eeyan ku ọgba awọn ologun ‘Signal Barack’ to wa ni Mile 2 ti ayẹyẹ nla ọhun ti waye.

Lati aago mẹjọ aarọ lawọn eeyan ti de ibi ti ayẹyẹ ọhun ti waye, nigba ti yoo fi di aago mẹta gbogbo ọgba awọn ologun yii ko gba ero mọ. Bawọn oloṣelu ṣe wa nibẹ, bẹẹ lawọn iyalọja ati babalaje kun ibẹ daadaa, bẹẹ lawọn oniṣẹ ọwọ, awọn oṣere atawọn ọtọkulu atawọn afẹnifẹre naa ko gbẹyin nibẹ. Awọn gbajugbaja sọrọsọrọ ori radio ati tẹlifisan nni, Ambasando Yọmi Matẹ ti gbogbo aye mọ si Ifa-kale-luya ati Alaaji Ganiyu Sẹbutu ni wọn dari ayẹyẹ yii.

 Adura lo kọkọ waye laarọ, nibi ti awọn aafaa nla ti rọjo adura fun Ajidagba ati gbogbo awọn eeyan ijọba ibilẹ Ifẹlodun. Yatọ si awọn olorin ti wọn da awọn eeyan lara ya, ami-ẹyẹ mẹrin ọtọtọ ni Ọnarebu Ajidagba gba lọjọ yii fun iṣẹ takuntakun to n ṣe . Kinni kan ti gbogbo  awọn eeyan n tẹnumọ ni pe aṣaaju gidi to nifẹẹ gbogbo awọn araalu,ti asiko rẹ tu tọmọde-tagba lara nijọba ibilẹ Ifẹlodun ni Ajidagba, wọn ni Ọlọrun lo gbe ọkunrin naa dide lati wa a tun ilu ṣe bii oye ti Ọba Ọjọra fi jẹ.
 
Lara awọn gbajumọ olorin ti wọn kọrin aladun lọjọ naa ni: Alaaji Abass Akande Obesere, Alaaji Abdulkabir Bukọla Alayande Ere Asalatu, Alaaji Rilwan Dosunmu, Oloye  Sulaiman Ayilara Ajobiewe, Alaaji Saidi Osupa, Kamoru Ishola Saridon 2,  Mukaila Senwele, Alaaji Ahmad Alawiye atawọn mi-in. Awọn osere mi-in ti wa tun wa nibe ni: Alaaji Kolligton Ayinla,  Alaaja Aminat Ọmọtayebi, Alaaja Rukayat Bashiri mi, Alaaja Azeezat Otibiya, Alaaja Modinat Asabi Barytide, Alaaji Nurain Akitunde, Alaaji Mumeen Damilọla, Tijani Adekọla Kamilu Kompo, Ọlaniyi Afọnja Sanyẹri, Murphy Afọlabi, Adebayọ Tijani atawọn mi-in. Osupa lo fi orin ka eto yii nilẹ.              

No comments:

Post a Comment

Adbox