IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 23 November 2019

Agba-oje osere tiata Yoruba, Otunba Awofe Afolayan fee sayeye ojoobi nla, Taye Currency, Barrytide,Lokoso Ajani ati Asimiyu Ajebori yoo forin dabira

Gongo yoo so niluu Eko lojo Eti, Fraide, to n bo yii, iyen ojo kokandinlogbon, osu kokanla yii. Agba-oje osere tiata Yoruba nni, to tun je oloye nla niluu Ila-Orangun, Otunba Awofe  Babalola Afolayan lo fee sayeye ojoobi, bee ni lo fee fun awon pataki lami-eye ati ifilole fiimu e tuntun.

Ile-Igbafe Lukman Hotel to wa ni Oke-Eletu niluu Ijede layeye nla ohun yoo ti waye. Awon olorin ti won yoo forin aladun da awon eeyan lara ya ni: Taye Currency, Modinat Ashabi Barrytide, Asimiyu Ajebori Gbafida, Apeke Ajobata, Ajani Lokoso,  Sanbo Fuji,  Xlic,  Tyson Wonder,  Bukky Praise,  ati Mukaila Senwele.

Ankara lawon eeyan yoo fi wole sibi ayeye naa, egberun meta ni ankara opa merin, nigba ti opa mefa je egberun marun-un. Eni ti yoo tuko ayeye yii ni Ajogbadola.

Lasiko  to n ba  Ojutole soro, Otunba Awofe ro gbogbo awon ololufe e lati fi ojo naa ye e si. O ni igbadun ti ko legbe lawon eeyan yoo je nibi ayeye yii.  
Fun alaye lekunrere, e pe nomba yii: 08023194659



No comments:

Post a Comment

Adbox