Bawo
ni egbe OPC se bere,ki lo pin egbe naa si yeleyele, se atunse si wa, e
gbo nnkan ti Ambassador Dare Adesope Aare egbe OPC Reformed so.
E je ka mo yin
Adesope: Oruko mi ni Ambassador Dare Adesope Aare egbe OPC Reformed
Nje e le salaye afibo "Reformed" iyen omo ti oruko egbe yin pon funwa
Adesope:
Reformed yen tunmo si nnkan ti a tun to,a ti se atunse to joju bee ni
iyato to han gbangba ti wa tawon eniyan si n jerii si pe egbe tiwa yato
Iyen nipe,bi Iba Gani Adams se yapa kuro leyin dokita Fasehun,ti eyin naa tun ti daro bayii, se kii se apeere aini isokan to
Adesope:
gbogbo enu ni mo le fi sope isokan ko Sonu ninu egbe OPC lotito Ida
egbe kookan loni adari tie bayii beeni atako maa n waye lapa ibikan bi a
ba ko iha to yato si nnkan kan sugbon bi ipe ba de lati ja fun aabo Ile
Yoruba,gbogbo wa la maa wa ni isokan toripe airinpo niije omo ejo niya.
Bi oka ba saaju ti paramole telee ti monamona nko laala leyin won,talo
je gbena woju omo ejo lona oko.
E je ka tubo mo yin daadaa.
Adesope:
Mo je okan ninu omo egbe OPC to duro deede, emi ni akowe gbogboogbo
egbe labe oloogbe dokita Frederick Fasehun sugbon nitori awon nnkan kan
to sele nigbayen ti mi o fe soro nipa e bayii,atipe egbe OPC ti n su
awon eniyan nigbayen latari iwa buruku tawon adari wa n hu,eyi atawon
nnkan miran lo bi egbe OPC Reformed.
Nipa awon iwa buruku tawon adari yin n hu nigbayen,se e le salaye e funwa
Adesope:
awon iwa kobetimu lawon tiwon pe ara won ni adari wa n hu nigbayen,won
yan owo dipo oruko rere, won lawon n jafun eto omo oodua sugbon apo won
niwon n ja fun.e wo nnkan to sele nigba ibo to waye lodun 2015, won ri
omo Yoruba nile,won o telee sugbon won gba lati tele eya miran nitori
owo. Won tun laya lati maa so o nigbangba pelu awon isongbe won pe,
eniti kiise eya Yoruba lawon tele,sebi eyin naa rii pe ofo niwon mu bo.
Latigba
yen ni emi gan an alara ti di ota oloogbe dokita Frederick Fasehun
toripe mo takoo aba won lati segbe fun eniti kiise omo Yoruba.
Boya ki e tan imole si nnkan to sele laarin eyin ati dokita Fasehun funwa daadaa.
Adesope: awon nnkan to sele laarin wa, ti di afiseyin ti eegun nfi aso. Awon nnkan ti mi o fe maa ranti mo ni toripe ko bojumu.
Awon nnkan ti ko se e maa ranti bi i:
Adesope:
baba fasehun ko toju ehin won daadaa rara. Ti o ba jepe won se afomo bi
eyin won se maa ri ni, eye tiko ba waye leyin iku re ko ba dara ti
gbogbo eniyan yoo mo pe eni nla lo. Baba niwon seleri lati gbe ijoba
egbe OPC funmi lasiko ti egbe ba nse ayeye Ogun odun ti a da a sile
sugbon toripe mo ko lati segbe leyin eya ti kiise Yoruba nigba idibo ti
baba si ti n polongo pe oun ni yoo wole, dokita Frederick Fasehun ba yi
ohun pada pe oun ko gbe ijoba sile mo. Eyin naa e wo bi ko ba ti yewon
to tobaje pe gbogbo wa si wa labe won nigbati olojo de.
Nibo le ti wa ri oogun ikiya lati kuro leyin baba Fasehun ti e si da duro laisi wahala
Adesope:
bi eniyan ba bere nnkan lori ododo,o daju pe Olodumare yoo wa leyin re.
Si iyalenu mi ijoba ibile merindinlogun la fi bere ti awon omo egbe si
duro wamuwamu. Ti a o ba je pe ao jamo nnkan kan ni,Kabiesi iku baba
yeye Alaafin Ile Oyo Oba Lamidi Adeyemi keta ko nii wa funmi ni opa ase.
Bawo ni aarin eyin ati Iku baba yeye Alaafin Ile Oyo?
Adesope:
Oba tii foba je ni baba wa Alaafin. Ajanaku koja mori nnkan firi niwon,
bi a ba peri akoni,aafi Ida hale gaaraga, kabiesiiiioooo! Yatosi pe won
je Ile isura asa Yoruba baba ni won je fun gbogbo omo kaaro oo jiire
patapata. Baba ni won je funmi,mo maa nlo bawon fun amoran beeni won maa
n tomi sona sipase ohun rere.
Nigbati iwe apeje
iwuye mi jade tawon kan ri oruko Alaafin nibe seni won n yinmu pe
Kabiesi konii wa sugbon baba bami jowon loju. Kabiesi wa beeni won tun
tete de pelu awon iko won,Kabiesi niwon gbe opa ase isokoso egbe OPC
Reformed lemilowo beeni won ni ki baba wa Oloye Ifayemi Elebuibon se
Iwure ati ibura fun emi atawon Oloye mi,sebi gbogbo wa naa la mo nnkan
ti baba Ifayemi duro fun.
E je ka fi sibikan die, ka soro nipa aabo,kinni eyin ri si bi aabo se ri ni orile ede yii to mehe?
Adesope: awon ijoba wa lo fa a
Lona wo?
Adesope:
gbogbo wa la mo bi awon alakatakiti esin o koku Boko Haram se bere,owo
yepere ni ijoba fi Koko mu oro won ki won to gba ile kan.ni bayii won ti di kaun tii ja obe koda Oro won ti su ijoba paapaa. Sugbon lero okan temi ago lo n da awon Boko Haram laamu
Ago lona wo?
Adesope:
se mekunnu lo se ni abi ijoba,kilode ti won o gba ile ijoba lo kiwon lo
hale mo won nibe tiwon kan n pa awon mekunnu danu lasan.
E je kafi iyen sile di ojo miran, ki le rope o le dekun iwa ibaje lawujo wa?
Adesope:
Ilana igbasejoba orile ede yii kole je ki iwa ibaje dekun lawujo wa,
koda awon ijoba wa gan an niwon n se atokun fun iwa ibaje. Eyin naa e wo
biwon se n da awon omo ile eko giga sile laini ise kan pato tiwon pese
sile funwon,awon tiwon n sise gan an alara o ri owo osu gba deede,won o
le jeun kanu koda Omoluabi ti o nitiju nikan ni konii jale bi oju ba da.
E wo bi awon oloselu se n nawo bi eleda, won a tun ko ohun ija oloro
fun awon odo lasiko ipolongo ibo bawo ni iwa ibaje se fe kase nile.
Nigbati e n soro aabo leekan,eo menuba rukerudo tawon eya fulani nda sile,kilode?
Adesope:
mo ti so fun awon eniyan wa ninu beba ati lori redio laimoye igba pe
awa la maa jafun aabo ara wa,sebi e ti gbo oro yen tipe latenu baba wa
oloogbe Obafemi Awolowo,bi a ba duro de ijoba seni Ogun maa teyin jawa
o. Ao le maa wo eni to mu ohun ija oloro lowo to fe pa wa,ki a si wo o
titi to fi gba emi wa. Nitemi o,bi enikan ko ba ro o leemeji ko to na
obe Simi,emi naa ko ni ro o leemeji ki n to gbeja ara mi pelu ohun
amusagbara Yoruba. Lasiko yii,gbogbo omo Yoruba gbodo fohun sokan lati
da aabo bo eya wa.o kan jepe gbogbo nnkan niwon ti toselu bo bayii,
gomina ipinle Oyo ogbeni Seyi Makinde nikan lo tako ki won ko Ile ijeran
fun awon eya kan ni Ile Yoruba, awon yoku ko soro toripe won Jo wa ninu
egbe oselu kan naa.
Bi a ba wa n soro nipa isokan,se e rope ipinya ko nii je akude fun egbe OPC bayii?
Adesope:
Bi a ba n soro nipa isokan, ohun kan soso la gbodo fi soro labe akoso
botiwu Kori,ede Yoruba saa ni gbogbo wa nso jade lenu yii kilo wa de ti
Oro isokan maa wa ta wa leti. Mo je enikan to fi ara ro awon omo egbe
OPC daadaa nigbati gbogbo wa si wa papo koda pupo ninu won la si jo nse
ore di asiko yii, torinaa mo nigbagbo pe ao gbodo barawa soro isokan ti.
Ki le lero pe o faa ti ojulowo omo Yoruba se n sa fun egbe OPC?
Adesope:
oju aye niwon n se bee iwa eke gbaa ni toripe nnkan tiwon n ko lojumomo
niwon n sa to loru. Kinni a n tan arawa si. Koda ni Ile okeere oruko
tiwon fun awa alawodudu ko bojumu latari iwa wa, kosi nnkan to se egbe
OPC,a yo kanda kuro ninu iresi ni bee ibi gbogbo niwon ti n ko adiye
ale,kanda wa ni soosi ati mosalasi sugbon nnkan to ba ti jemo ti Ilana
ibile nikan ni won maa n pariwo.
No comments:
Post a Comment