IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 31 May 2019

O GA:NITORI PE OBINRIN KO O SILE,MAYOWA PA ARA RE L'EKOO

Kayeefi niku omokunrin kan toruko e n je Mayowa je fun gbogbo awon eeyan to gbo pe o gbe majele  je nitori pe afesona e ti won ti fera fun odun mesan-an so pe oun ko se mo.

Ale ojo Aiku, Sannde, anaa ni Mayowa gbe oogun ti won fi n pa kokoro ti won n pe ni 'sniper' je, ti kinni ohun si gba emi e lesekese.

Ojutole gbo pe saaju ki Mayowa too pa ara re lo ti koko gbe e fidio ara re sori eka ayelujara ti won n pe ni 'facebook' pe oun yoo pa ara oun pelu oogun kokoro yii.

Awon to mo Mayowa sapejuwe e gege  bii omo kan to ni ojo ola gidi, won lo mowee daadaa, bee le je akinkanju eeyan. 


No comments:

Post a Comment

Adbox