IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 1 June 2019

LEYIN TO PARI ILE OLOWO NLA, GBAJUGBAJA OLORIN EMI, MEGA 99 RA MOTO RANGE ROVER EVOGUE

Inu idunnu ati ayo ni gbajugbaja olorin emi ati juju nni, Omooba Abel Dosunmu ti gbogbo aye mo si Mega 99 wa bayii. Ko si ohun to fa idunnu fun osere nla tawon eeyan feran daadaa yii ju moto olowo nla toruko re n je 'Range Rover Evogue' to sese ra lo.

Ojutole gbo pe ni nnkan bii ojo meloo kan seyin ni Mega 99 ti won tun n pe ni Ogo Sele tabi Omo Iyawo Jesu ja ora lara moto boginni yii.

Bakan naa la tun gbo pe wolii nla nni, Prophet Israel Ogundipe tawon eeyan mo si Genesis lo koko sadura si moto yii. Ninu oro Genesis lo ti sapejuwe Mega bii oniwa irele eniyan, ti ko jo ara re loju, bee lo sadura fun Mega 99 pe emi re yoo lo oko yii, ti yoo tun ra eyi to dara ju eleyii lo.

Ti e ba gbagbe, ni nnkan bii osu meloo kan seyin lawon omoose Mega 99 tu asiiri ile olowo nla to ko siluu Eko, ojo ojoobi e ni won ya foto ile yii, ti won ju u sawon oniroyin.

 Awa naa ba Mega 99 dupe lowo Olorun fun oore ayo ti Olorun se fun un yii, oore otun yoo tunbo sele nile e. 














No comments:

Post a Comment

Adbox