Ojo nlaAlayeluwa, Oba Abdulfatai Oyeyinka Aremu Ojora tile atawon gbogbo ara ilu naa ko ni I gbagbe boro lojo kin in ni osu kin in ni, odun tuntun ti a wa yii.
Ojo yii
ni oba alade nla yii sayeye ojoobi odun kerindinlaaadorin to dele aye,ohun to
tun je ki ojo naa larinrin ni pe kabieesi tun fi oye da awon eeyan Pataki
lawujo kan lola. Lara awon ti Ojora fi joye lojo yii ni Alaaja Taibat Ijelu Oke-Owo joye
Iyalaje gbogbo ilu Ijora. Nitori ipa nla ti onisowo pataki yii ko fun idagbasoke ati ilosiwaju ilu Ijora ati ipinle Eko lapapo ni won se fi joye nla yii.
Awon eeyan pataki lawujo ni won tele Iyalaje tuntun yii wa saafin Ojora lojo ti won jawe oye le e lori.
Adura lawon musulumi koko fib ere eto ayeye yii lojo
naa,leyin ni kabieesi jawe oye le awon oloye atawon baale tuntun lori. Yato si
Alaaja Taibat to joye, alaga ijoba ibile idagbasoke Ajeromi-Ifelodun, Alaaji
Shuhaib Fatai Ajidagba naa joye Atunluse ati Atunlunto iju Ijora.
Leyin ti Kabieesi fawon oloye e tuntun joye tan, ni won ge
akara oyinbo ti won ti pese sile fun ayeye ojoobi ohun, ti gbogbo ilu Ijora dun
yungbayungba.
Gbajugbaja akorin apala nni, Alaaji Musiliu Haruna Ishola lo
forin aladun da awon eeyan lara ya, tawon eeyan fese rajo orin apala gidi
latenu oga awon olorin apala yii.
Ohun to
foju han nip e ojo yii ye Oba Abdulfatal Oyeyinka Aremu,ki baba se opolopo odun
laye ninu ola,owo ati alaafia repete.
No comments:
Post a Comment