IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday 27 December 2018

OPE O: BIDEMI OMO JIDE KOSOKO SE MOMI-N-MO-O, ODUN TO N BO NI YOO SEGBEYAWO ALARINRIN

Inu ayo ati idunnu nla ni agba-oje osere tiata Yoruba nni, Omooba Jide Kosoko, wa bayii, okan ninu awon omo e toun naa je osere tiata, Bidemi Kosoko lo se momi-n-mo-o ti won n pe ni 'Introduction' lede oyinbo lanaa. 

Ile baba e to wa niluu Ikorodu layeye naa ti waye. Okunrin ara orile-ede Amerika la gbo pe Bidemi ba lo. Odun 2019 ta a fee mu yii la gbo pe won yoo se igbeyawo gangan.







Lara awon osere to wa nibe lojo naa ni: Oga Bello, Yinka Quadri, Remmy Shita Bey atiyawo e, Funmilayo, Olaiya Igwe, Kola Olaiya, Iya Awero, Ishola Taiwo, Sola Kosoko Abina atoko e atawon mi-in. 

No comments:

Post a Comment

Adbox