IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 10 March 2026

Tunde Lẹmọ ọna tooro to wọ Oke-Mọsan lọdun 2027


Bi ojumọ ṣe n mọ bẹẹ ni eto oṣelu fun ibo ọdun 2027, sunmọ etile tawọn araalu si ti n woye ẹni ti wọn yoo dibo wọn fun gẹgẹ bi adari tuntun fọdun mẹrin mii-ii.

Bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri nipinlẹ Ogun lori ibo gomina ti yoo waye tawọn oludije si ti n jade lati fẹẹ dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu wọn.

Ki i ṣe tumtun mọ pe awọn kan ti jade lati dupo gomna labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, lara wọn si ni Tunde Lẹmọ, igbakeji ọga agba banki ilẹ wa tẹlẹ, ti okiki si ti kan kaakiri pẹlu bi iṣẹ ṣe n lọ.

Amọ gẹgẹ bi ẹni oye oṣelu, ohun tawọn araalu maa n fẹ lẹni ti yoo mu igbe aye wọn rọrun, ti yoo pese awọn nnkan ti wọn ba fẹ lakooko, ti ọrọ aje yoo maa lọ, bo ṣe yẹ, ti yoo pese ọna to ja gaara fun wọn.

Idi niyii ti wọn fi sọ pe Tunde Lẹmọ kaju ẹ pẹlu awọn iriri to ti ni sẹyin latigba ti wọn ti bi, atawọn ipo nla to ti di mu.

Ẹni ti ọpọlọ ẹ pe nipa isakoso ilu ni wọn pe Tunde Lẹmọ, nipa isakoso ilu, ati b olori ṣe le wa ipenija sawọn isoro imayedẹrun lọna tawọn araalu yoo fi wa ni irọrun.

Bi ẹ ko ba mọ lẹyin iṣẹ banki to ti di ọga, bẹẹ nijọba aarẹ ana,Mohammadu Buhari, tun fi jẹ  alaga awọn to tun ọna ṣe iyẹn FERMA, lọdun 2017,  to si bẹrẹ iṣẹ pẹlu awọn igbimọ ẹ lọdun 2018.

Titi di akoko yii, akọsilẹ rere si wa pẹlu awọn ọna ti wọn ṣagbatẹru ẹ lorileede yii. Awa naa si mọ pe pẹlu bawọn ileeṣẹ nlanla ṣe wa nipinlẹ Ogun, iṣoro kan ṣoṣo to n koju wọn ni ọna lawọn bii Ọts, Sango,Agbara, Ijẹbu Ode, atawọn ibo miii.

Ohun to si jẹ gboogi to kọ Tunde Lẹmọ lominu ni baye yoo ṣe dẹrun lara wọn si ni ọna,eyi to ni lọkan lati ṣe to ba de ijọba. Idi tawọn agba nidii oṣelu to fi mọ awọn araalu fi sọ pe ọkunrin yii nikan lọna tootọ lati ṣejọba ni Oke Mọsan lọdun 2027.

No comments:

Post a Comment

Adbox