Taofik
Afolabi
Olori ijo ‘One Love Family’, Satguru
Mahara J Ji, ti so o di mimo pe ahamo awon olopaa lo ye ki baba olowo orile-ede
yii, Alaaji Aliko Dangote wa bayii, nitori pe iwa
to buru jai ni bi okunrin olowo naa se ba oko ati ile awon eeyan ilu Akon,
nipinle Nasarawa je nitori ileese suga to fee ko sadugbo yii.
Satguru
Maharaji ji ni ohun ti Dangote se yii ko yato si iwa odaju eeyan, ti ko feran
omolakeji e, peluu bo se so awon eni eleni di eni ti ko nile lori, to so won di
alarinka ninu ilu won.
Mahara Ji ni
to ba je pe awon ijoba wa feran awon araalu, ti won ko fe wahala fun won, o ye
ki Aare ti ju Dangote sahaamo awon olopaa tabi ogba ewon bayii.
The Perfect
Living Master, gege bawon eeyan se tun maa n pe so pe o ye ki Dangote ranti pe
Olorun lo fun un lowo,ko si ye ko fi owo naa ni awon araalu lara, nitori pe
Olorun to fun un lowo ko so pe ko fi hu iwa ika fawon to ku die kaato fun.
O te siwaju
ninu oro re pe se lo ye ki Dangote wa ibo mi-in fawon eeyan yii leyin to ti ba
ibi ti won n gbe je, to so won di eni ti ko nile lori, tawon eeyan di
alasunkiri ilu.
No comments:
Post a Comment