Bi eto dibo odun to n bo se n sunmo etile, tawon oloselu ti bere ipolongo won, egbe onimoto nipinle Eko, iyen ‘National Union of Road Transport Workers’ (NURTW) labe alaga won, Alaaji Tajudeen Agbede, ti seleri atilieyin nla fun oludije ipo gomina labe egbe oselu APC nipinle Eko, Ogbeni Babajide Olusola Sanwo-Olu tawon eeyan tun n pe ni Sanwo-Eko.
Alaaji Agbede ni ' Ti a ba wo o daadaa, a o ri i pe ninu gbogbo awon oludije ipo gomina nipinle Eko, Sanwo-Olu lo kunju osuwon lati se gomina. Oun ni yoo mu igbe-aye irorun ba gbogbo wa, ti ko yoo si mu ilosiwaju ati idagbasoke otun ba ipinle Eko'.
Bakan naa lo ro awon egbe yooku bii egbe awon olokada atawon egbe awon onikeke Maruwa lati satileyin fun Sanwo-Olu ki gbogbo ara Eko le je mudunmudun ijoba gidi latowo okunrin naa.
Ninu oro e, adari gboogboo fun eto ipolongo ibo fun Sanwo-Olu, Ogbeni Tayo Ayinde, dupe lowo awon omo onimoto yii fun bi won se setan lati ti Sanwo-Olu leyin, paapaa moto ti won ti ta okunrin naa lore fun ipolongo ibo.
O ni anfaani nla ni atileyin tegbe onimoto yii se fun Sanwo-Olu je, awon si mo riri ohun ti won se yii.
O sapejuwe Alaaji Agbede bii asaaju gidi to ti mu ayipada rere ba ise moto nipinle Eko, eyi ti ko fi si wahala kankan ninu egbe naa mo. .
No comments:
Post a Comment