Okan ninu awon olorin Islam toruko won rinle daadaa lorile-ede yii ni, Hajia Zainab Bolanle Otaru, lojokojo ti won ba n daruko awon akorin esin Islam ti won mo tifun-tedo orin, o daju saka won yoo daruko omooba ilu Okene, nipinle Kogi yii si i.
Ohun ti a gbo bayii ni pe arewa akorin esin naa sese gbe orin kan jade to pe akole re ni 'Wa a gbe mi ga', orin naa to ti gbayi lori ero ayelujara ati ori radio lawon musulumi ododo fi n jaye orin won bayii.
Orin aladun yii ni gbogbo awon eeyan ti won n fe igbega lodo Olorun n gbo bayii, gbogbo awon eeyan ti won ti gbo o ni won kan saara sise opolopo,won ni orin ti gbogbo awon musulumi ododo gbodo ni nile won ni.
Saaju akoko yii losere yii koko ti gbe orin kan to pe ni “Ma a-de-niyan” jade, bee la gbo pe o ti n ya fidio.orin naa lowo bayii, o si ti fokan awon ololufe e bale pe oun ko ni i da won lagara ti fidio naa ba jade.
Lasiko to n ba Ojutole soro, Hajia Bolanle ni 'Adupe lowo Olorun gbe awon eeyan tewo gba orin wa tuntun yii, gbogbo awon eeyan ti won ti gbo o ni won so pe ise opolo ni, mo si fi da won loju pe mi o ni i ja won kule laelae.
.
Fun gbogbo awon eeyan to ba fee gbo orin Mad’eniyan , e le e wo o lori aforan yii.https://youtu.be/X1g_BJ5Zkeg
No comments:
Post a Comment