IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 8 October 2018

OJO TOSDE LAYEYE 'YORUBA FILMS AND MUSIC FESTIVAL' YOO BERE

 eto lo ti pari ninu ayeye gbigbe orin ati fiimu Yoruba laruge ti won pe ni 'Yoruba Films and Music Festival' eleekeji iru e. 

Ojo Tosde, ojo kokanla layeye naa yoo bere ninu gbongan 'Blueroof' to wa ninu ogba ileese telifisan LTV,to wa ni Ikeja,  ti yoo si pari lojo kejila, ojo Eti, Fraide.

Ayangburen tiluu Ikorodu, Oba Abdulkabir Shotobi, ni yoo saaju awon oba alaye yooku lati siso loju ayeye yii. Awon olorin, awon elere ori itage atawon eeyan pataki lawujo ni won reti nibi ayeye yii.

Ninu oro oludasile ayeye naa, Otunba Omotayo Ogunlade lo ti so pe ayeye todun yii yoo larinrin ju todun to koja lo. O ni awon olorin yoo forin aladun da awon eeyan laraya, bee lawon eeyan yoo lanfaani lati ra awon orin ati fiimu atijo lojo naa.



No comments:

Post a Comment

Adbox