IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 8 October 2018

BABA AWON OSERE ALAWADA, BABA SALA TI KU O, LEYIN TO SE ISIN NI SOOSI LO DAGBERE FAYE


Iroyin to te Ojutole lowo bayii ni pe baba awon osere alawada lorile-ede yii, Alagba Olaiya Adejumo ti gbogbo aye mo si Baba Sala ti ku, irole ojo Aiku, Saande, ana, lo jade laye.
Ojutole gbo pe lojuese ti baba yii ku ni won ti loo toju oku e pamo si yara igbokuusi ile ile iwosan 'Wesley' to wa niluu Ilesa. Eni odun merinlelogorin ni baba naa kolojo too de.
Gege bi a se gbo, Baba Sala lo si soosi e laaro ojo Sannde to ku yii, koda oun lo sadura ipari isin, ti ko si apeere pe olojo ti de.
E o ranti pe o to emeeta otooto laarin odun merin ti won fi so pe baba yii ku, sugbon to je pe iroyin eleje lasan ni.
Gbogbo bi eto isinku naa y

oo ba se lo ni Ojutole yoo fi to yin leti.

No comments:

Post a Comment

Adbox