IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 17 September 2018

SEGUN AYENSORO REE O, ODOMODE OLORIN EMI TO N SE BEBE

Okan pataki ninu awon olorin emi ati juju tawon eeyan feran daadaa ni lasiko yii ni Segun Ayensoro. Odomokunrin, omo bibi ilu Ikenne, nipinle Ogun yii naa ki i seni teeyan yoo foro ro seyin lagboole orin.

Omo odun meta pere ni Segun wa to ti n korin, orin to saaba maa n ko o nigba naa  ni 'Aye -n-soro', aye -n- soro ooo' orin yii lo pada waa di oruko tawo eeyan fi n pe e  bayii.

Lasiko to n ba Ojutole soro, Aye-n- soro to sese gbe awo re akoko o pe ni 'Je-kaye-mo' jade so fun wa pe opo awon olorin juju ati temi-in loun wo lawokose, sugbon enikan to wu oun lokan ju lati ba korin papo laye oun ni Omooba Abel Dosunmu tawon eeyan mo si Mega 99, o ni okunrin naa je iwuri nla foun lagboole orin.     

Okunrin yii toruko egbe orin re n je Barnaba Music so pe ko si ode ariya ti won pe oun si lati waa korin toun ko ni i lo sibe, nigba toun ko nise mi-in ju orin kiko lo.

Nipa rekoodu e to gbe jade, o salaye fun wa pe imisi latorun wa lawon orin to wa ninu e. Lara awon orin aladun to wa ninu awo naa ni 'Baba lo pe mi, Jeyayemo,  Mo segun lo n pede, Saanu mi ati Oluwa lo mogba aye mi'.

Bakan naa lawo yii wa ni gbogbo ibi ti won ti n ta ojulowo rekoodu. E pe Segun  Ayensoro sori nomba foonu yii 0703 721 5095 tabi  08125756902  fun ode ariya.  

No comments:

Post a Comment

Adbox