Lasiko to n tu asiiri yii, Osupa ti won tun n pe ni Matagbamole so pe awon alakowe ti won n gbe ni Magodo toun kole si ni won gba oun nimoran pe koun ma ba onifuji kankan ja mo, ile-ejo ni koun maa gba lo, dipo boun se maa n bawon ja tabi bu won sinu rekoodu.
O ni lasiko tawon alakowe yii ba n sare koja niwaju ile oun ni gbogbo ojo Abameta, Satide ni won maa n ri oun niwaju ile oun, ti won si maa juwo soun.
O ni lara awon alakowe yii ni won waa ba oun ti won foun nimoran atata yii pe ile-ejo ni koun maa gbe onifuji to wa wahala oun lo. Osupa ni awon alakowe yii won foun logbon yii latigba naa loun ko si ti ba onifuji kankan fa wahala mo.
No comments:
Post a Comment