IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 5 September 2018

OJISE ESU KAN REE O: WON KA PASITO MO IBI TO TI N KO IBASUN FUN IYAWO ONIYAWO LORI OKE N'IBADAN

Titi di bi e ti n ka iroyin yii,  loro pasito kan ti won pe oruko e ni pasito Osho  ti won ka mo ori okan lara awon omo soosi e ti won jo n ba ara won sun karakara ninu igbo si n je kayeefi nla fun won.


Gege ba a se gbo, obinrin naa ti won pe ni oruko e ni  Ajibade la gbo pe o lo sori oke ti pasito naa wa lati loo gbadura ataawe olojo meta, sugbon to je pe kaka ko kojumo nnkan to ba lo, nnkan min-in lo n se nibe.

Ohun ta a gbo ni pe gbara ti Arabinrin Ajibade  de ori oke naa ti to wa  niluu Ibadan lawon kan ti funra si i, paapaa pelu isesi oun ati Pasito Osho.

Nitori e la gbo pe awon eeyan naa fi bere si ni so won lowo-lese lati mo nnkan to pa won po, sugbon tasiri won pada tu sita lopin ose to koja yii.


Inu igbo kan nitosi ori oke naa ni Pasito Osho ati Arabinrin Ajibade gbe ara won lo, ti won si n gbe nnkan sara won labe, ti kinni naa si n dun mo won daadaa.

Lara awon to topinpin awon mejeeji de inu igbo naa la gbo pe o gbe foonu e lati fi ya won nile ti won ti n ko ibasun funra won karakara.

Nigba to maa to iseju die tawon mejeeji ti n ba ara sun ni eni naa je ki won mo pe oun ti n wo won tipe, Bi pasito naa si se ri i pe wahala nla ni fidio naa yoo je fawon mejeeji lo mu ko fe e fipa gba a, ko si paare, sugbon tiyen so oro naa dariwo nla.

Iyalenu lo je fun opo awon to wa a gbadura ni ori oke naa, to mu ki won maa gbe pasito naa sepe nla, ti won si n benu ate lu u pe awon iranse esu ti won n foruko Olorun boju ni.

Lesekese la gbo pe won ti gbe fidio naa sori ero ayelujara, tawon eeyan si bere si i pin in kaakiri lati le je ki won mo iru ori oke ti won yoo ti lo maa gbadura dasiko yii.

Sa o, titi di Bi a ti sakojopo iroyin yi tan la gbo pe Arabinrin Ajibade to dagbere ko too kuro nile e pe oun fe e loo gbadura ati aawe ni ori oke si na papa bora, ti ko si seni to le so ibi to gba lo.

Bee la gbo pe won ti da Pasito Osho duro lori oke naa, toun naa si tisa lo.

Afikun iroyin: IROYIN AWIKONKO

No comments:

Post a Comment

Adbox