IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 2 September 2018

ODIDI ODUN MOKANLA NI MO FI WA OKADA NIGBORO EKO, FASOLA NI KO JE KI N KU SABE TIRELA-PAUL OMO ABULE

Okan ninu awon gbajumo olorin emi lorile-ede yii ni Efanjeliisi Friday Paul ti gbogbo aye mo si Omo Abule. Opo rekoodu lo ti gbe jade, bee lo ti gba opo ami-eye nidii ise to yan laayo.

Ko seni ti ko mo orin okunrin naa to ko bayii pe 'Lojo kan ni won oo loo royin mi labule pe emi naa ti soriire'. Sugbon opo ni ko mo pe odidi odun mokanla lokunrin naa fi gun okada nigboro Eko, to n fi okada sise oojo e, bee lo si tun korin lapa kan.

Funra osere nla yii lo tu asiiri yii lori eto 'Owuro La wa' ti won maa n se lori telifisan LTV. Ninu iforowero ti won se fun un lo ti so bayii pe ' Odidi odun mokanla ni mo fi gun okada,ti mo n fi okada sise jeun,sugbon nigba tijoba fofin de awon olokada,ti wahala awon olopaa po ni mo fi okada gigun sile'.
  

No comments:

Post a Comment

Adbox