IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 4 September 2018

KO SELE RI, QUEEN SEIDAT ALMUBARAQ, OLORIN ISLAM, FI KAMERA OLOWO IYEBIYE YA REKOODU E, 'RED CAMERA' NI WON N PE E

Ohun ti ko sele ri laarin awon olorin Islam lorile-ede yii ni gbajugbaja olorin esin, to tun je aafaa nla, Queen Seidat Almubarak mu wo orin naa bayii. Kamera olowo iyebiye, ti ko ti i si olorin Islam to lo iru e ri lobinrin naa fi ya fidio rekoodu kan to fee gbe jade.

Kamera yii ti won n pe oruko re ni 'Red Camera' ni ilu mo on ka adari fidio, Ogbeni Dare Zaka fi n ya rekoodu naa fun Queen Almubarak. Ketekete bayii lo ri, to je pe ti eeyan ba so abere sile yoo ri i ni fidio ohun.

Yato si eyi, bi won se ya fidio rekoodu naa ni l'Ekki niluu  Eko, bee ni won tun ya a niluu Abuja. Bakan naa la gbo pe Queen Seidat tun lo moto  awon olowo ti won n pe ni Limousine ninu fidio yii.

Iyen nikan ko, awon aso ti ko ti i si olorin Islam to wo iru e ri ni Queen wo ninu fidio yii, bee lawon omoose  e ti won wa ninu e naa mura lona to ba esin mu.

Papanbari e ni pe opo orin ologbon, orin oloye, orin ti gbogbo eni ti alujanna ba je logun gbodo maa gbo lo wa ninu orin yii.

Kinni kan to foju han ni pe ti fidio naa ba jade, yoo pe e daadaa, ka too ri fidio ti yoo ba a nitori pe obitibiti owo ni won fi ya a.



No comments:

Post a Comment

Adbox