IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 5 September 2018

HAA, OJU PA KASUMU ONITIATA KO RINA DAADAA MO

Iroyin to ba ni lokan je to te wa lowo nipa agba-oje osere tiata Yoruba nni, Alagba Kayode Odumosu tawon eeyan mo si Pa Kasumu ni pe oju okunrin naa ko rina daadaa mo.
Lasiko to n ba iroyin Awinkoko soro lokunrin naa salaye bayii 'Aisan to n se mi ni i se pelu oju mi, mi o riran daadaa bii ti tele mo. Nnkan maa n di pupo loju mi ni. Bi e se duro ti e n ba mi soro yii, se lo da bii pe eyin meji le e duro niwaju mi. 
Mo fe e dupe lowo omo mi. o duro ti mi pelu orisirisi adojuko ati ipenija, to n mu mi lo lati-ibikan si ibomin in. mo ti lo s’ibi kan ti won ti n se oju n’Ikoyi. Mo ti lo si India fun itoju. Odun mesan seyin ni wahala yii bere, iyen lojo kesan-an, osu kejila, odun 2009.
Nigba to bere, omo mi nikan lo duro ti mi, o je omo to ni irele. Mo n san egberun merinlelogbon (34,000) naira si egberun merindinlogoji (36,000) naira lose-ose fun itoju. Nigba yen, mo si ni awon owo kan ninu apo ile ifowopamo (Bank Account) mi, mo ri awon owo yen pelu bi mo se gba’le-gba’ta. O ye ki n na owo yen, sugbon mo fe e fi owo naa kan paanu ile mi ti mo n ko si agbegbe Ogijo ni, owo naa to milionu merin (#4) naira. Sugbon nigba ti aisan yi de, gbogbo owo yen lo lo si patapata'.

No comments:

Post a Comment

Adbox