IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 26 September 2018

GBAJUMO OSERE TIATA YORUBA, YOMI FABIYI FIFE HAN SOKAN NINU AWON OLOLUFE E

Gbajugbaja osere tiata wa, to tun je onkotan, Yomi Fabiyi, fife han si okan ninu awon ololufe e loni-in. Ohun to sele ni pe bi okan ninu awon ololufe  Yomi se ri i lo so fun un pe o wu oun lati ba a ya foto, sugbon nitori  pe ara oun doti nidii ise ti oun se, oun gbadura pe ki Yomi si wa ladugbo yen nigba toun ba ti we, toun si ti paaro aso oun.

Lojuese ni Yomi so fun un pe ko ma wule da ara re laamu lati loo we tabi paaro aso e,  o ni ko sunmo oun kawon jo ya foto naa, nitori pe idi eni ni won ti i mo ni lole, won ko si fakoko sofo ti won ya foto ohun. 

Ohun ti osere omo bibi ilu Abeokuta yii se lagbo pe o dun mo ololufe e yii nnu, nitori pe ko ro o lokan pe Yomi yoo gba lati ba oun ya foto pelu aso to doti

naa. 

No comments:

Post a Comment

Adbox