IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 22 September 2018

GBAJUMO OLORIN ISLAM,MUMEEN DAMILOLA ATIYAWO E TUNTUN BIMO OKUNRIN

Iroyin ayo to te wa lowo ni pe iyawo tuntun ti gbajumo olorin Islam nni, Alaaji Mumeen Damilola segbeyawo pelu e lodun to koja ti bimo okunrin.

Aaro ana, ojo Eti, Frade la gbo pe ohun ayo yii sele, tawon eeyan si ti n ki toko-taya yii ku oriire.

E o ranti pe gbajumo olorin Islam mi-in, Alaaja Mujeedat ni Damilola fe nisu-loka, ti won si bi omo merin, ko too di pe wahala sele laarin won, tawon eeyan naa si pinya.

Ipinya yii lo je ki Damilola segbeyawo alarede pelu obinrin mi-in, leyin e ni Mujeedat naa segbeyawo pelu okunrin onisowo kan. 

No comments:

Post a Comment

Adbox