Ogunlogo awon ololufe gomina ipinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambode ni won tu jade bii esu lati sewode pe eyin okunrin naa lawon wa digbidigbi. Iwode ohun lawon eeyan naa ti gbe akole orisiirisii dani, Ikeja ati Ojuelegba ni won ti se e.
Awon alatileyin ati ololufe Ambode yii ro Tinubu,to je asaaju egbe oselu APC lati gbe ohun to n sele laarin oun ati Ambode wo daadaa,nitori pe omo ati baba ni won.
Awon oluwode yii fi kun oro won pe gbogbo aye lo mo pe Ambode ti sise takuntakun laarin odun meta aabo to ti wa lori aleefa gege bii gomina ipinle Eko, ko si ohun to dara ju ju pe ko lo odun merin mi-in lo,ko le pari gbogbo awon ise akanse to ti dawo le.
No comments:
Post a Comment