IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 22 August 2018

WAHALA TUNTUN NINU EGBE ANTP, WON YO VICTOR ASAOLU NIPO AARE

Wahala mi-in tun ti beyo ninu egbe awon osere tiata Yoruba ti won n pe ni 'ANTP,' pelu bi won se yo aare egbe naa, Komuredi Victor Asaolu nipo.

Ose to koja yii lawon omo egbe naa sepade nla kan ti won ti yo aare won yii, eyi to waye ni gbongan asa ti won n pe ni 'Cultura Centre' to wa niluu Ibadan.

Lojuese la gbo pe won ti yan elomi-in gege bii aare fidii-he egbe naa. Lara awon asaaju egbe naa to wa nibi ipade yii ni:Baba Geebu, Eda Onileola, Itu Baroka  ati Sakiru Alogbon.

Bakan naa la gbo pe  Alogbon to figba kan se gomina egbe naa nipinle Eko ti so pe oun yoo gbe Asaolu lo sile-ejo lori bo se
dari egbe naa, nigba to wa nipo aare.

Ibi ti oro yii yoo ja si ko seni to mo.

No comments:

Post a Comment

Adbox