IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 27 August 2018

OWO TE AJINIGBE TO SE N BII WERE L'AKURE, FOONU MEJI NI WON BA LOWO E

Owo awon eeyan ilu Akure, nipinle Ondo ti te okunrin kan ti won ro pe were ni lati odun yii wa,sugbon to je ajinigbe ni. Lasiko towo te e laduugbo kan ti won n pe ni Orita Obele Estate lo jewo pe oun ki i se were, o ni ajinigbe loun ati pe lati ipinle Edo loun ti waa sise ibi naa niluu Akure.
Foonu meji la gbo pe won ba lowo okunrin naa, ko too di pe won fa a le awon fijilante lowo. Enikan ti sele yii soju e so pe nigba tawon eeyan fiya se tie lo jewo pe ki won se oun jeejee, sugbon o ko lati daruko awon to n ran an nise aburu yii.
Odo awon olopaa la gbo pe okunrin naa wa bayii,nibi to ti n ran won lowo lori iwadii won.

No comments:

Post a Comment

Adbox